Smiley face

“Lilo ileewe fun ipatẹ ariya nipinle Eko ti deewọ”- Ambode



*Ambode fẹ ra ẹrọ ayarabiasa pelebe 324, 000 fun awon akekọọ
Akinwunmi Ambode
 Ijọba ipinlẹ Eko ti kede wi pe, ko saaye fun awọn alariya lati maa lo inu ọgba ileewe fun ipatẹ ariya mọ ni ipinlẹ Eko. Iru asa bayii ni ijọba ipinlẹ Eko salaye gẹgẹ bi ohun ti n tabuku ilọsiwaju eto ẹkọ ni awujọ wa.


Aṣa pipatẹ ariya sinu ọgba ileewe yii ni igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Idiat Adebule, koro oju si nigba ti n salaye awọn igbesẹ Gomina Akinwunmi Ambode fun awon oniroyin nipa eto ẹko ọdun 2016.

Arabirin Adebule ni awọn ofin tuntun yii ko taba awọn ileewe ijọba nikan, bikose pẹlu awọn ileekọ aladani ti won kalẹ si ipinlẹ Eko.



“Gomina ipinlẹ Eko ti paṣẹ wi pe, ileekọ kankan ko gbọdọ jẹ fun gbagede ariya mọ. A si n fi asiko yii ke si awon eniyan awujọ la ti ta wa lolobo nikete ti won ba kofiri ileewe kankan to tapa si ofin ijọba," Adebule fi  kun ọrọ rẹ bẹẹ.

Arabirin Adebule to tun jẹ adari ẹka ileesẹ ijọba ti n risi eto ẹkọ  so wi pe, nnkan ti yatọ si ti atijọ. Idasilẹ ileewe fun awon aladani ti kuro ni ohun ti won le ri gẹgẹ bi okoowo ti yoo kan maa pawo wọle lasan lai bikita ojulowo ẹkọ to yanranti. Ninu oro naa lo ti n sọ wi pe, ijoba to wa lode yii ko ni faaye gba yọbọkẹ.

“Aimoye awon ileewe aladani lo ti kun igboro lode toni. Ijoba ko si ni yaju sile ki talubọ o ko wọ ọ nipa fi faaye gba awon ileewe ti ko koju osuwon. Aimoye awọn ileewe lo wa to jẹ wi pe, won ko gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba. Ti awon iru ileewe bayii ba kọ lati se ohun to yẹ kan se, ijoba naa ko ni fa sẹyin lati se ohun to to fun won. Sebi awifuni ko to dani ni Yoruba n pe lagba ijakadi, " Adebule fidi ọrọ gunlẹ bẹẹ.


Bakan naa, oludamọran nipa eto ẹkọ fun Gomina Akinwunmi Ambode, Ọgbẹni Obafela Bank-Olemoh, sọ wi pe gomina ti setan lati kọ yara ikowesi onidigita to tobi julo. Ninu afikun ọrọ rẹ, o ni ijọba tun setan lati kọ ileewe igbalode bi mẹwaa nibi ti awọn akẹkọọ yoo ti ma kọ nipa iṣẹ ọna ati imọ ẹrọ igbalode.

Ọgbẹni Obafela ko sai mẹnu ba akanse eto ipese ẹrọ ayabiaṣa pelebe ti won pe ni “Ibilẹ Tablets” bi ẹgbọrun lọna ọọdunrun ati mẹrinlelogun (324,000) ti Ambode setan lati pin fun awon ọmọ ileewe girama to wa nipinle Eko. Awon eto tuntun eleyii to mu imọ ẹrọ ayarabiaṣa igbalode dani ni won lero wi pe yoo ṣe ọpọlọpọ iranlọwọ fun awon akẹkọọ.

Ọgbeni Obafela tun sọrọ nipa ounjẹ ofẹ ti ijọba seleri nigba eto ipolongo rẹ.
Eto n lo lọwọ labenu. Gbogbo eto ni ijọba si n ṣẹ lati ri wi pe, akanse eto ounje ọsan ọfẹ naa fun awon akẹkọọ kẹsẹjari nipinle Eko. Mo fi n dayin loju wi pe, eto yii yoo bẹrẹ laipe,” Ọgbeni Obafela fikadi ọrọ rẹ nilẹ


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment