*Wale Dada ni ojiṣẹ Ọlọrun ni gomina
"Ohun idunnu julọ ati
ẹkunrẹrẹ ayọ ni imuṣẹ awọn ileri wa si awọn eniyan awujọ. Eleyii ti yoo ni ipa
to jọju ninu igbe aye wọn, ti yoo si mu igba rọrun fun tẹru-tọmọ" Eyi ni
ọkan lara awọn ọrọ iwuri ti gomina Ibikunle Amosun fi side idupẹ rẹ nigba ti awọn
eniyan wa ba yọ ayọ ọjọ ibi ọdun mejidinlọgọta (58) to ko lọjọ Aje to kọja yii (25/1/15).
Aimọye awọn eniyan ni wọn pejọ si June 12 Cultural Centre, Kutọ to wa ni
Abeokuta lati wa ba gomina yọ. Gbogbo wọn naa ni wọn si n gbe sadankata fun
aseyọ iṣẹ takuntakun Amosun nipinlẹ Ogun eleyii ti ko lẹgbẹ.
Wayio, ogbontarigi sọrọsọrọ
ori rẹdio ati telifisan, Adewale Dada Thegood ti ṣe alaye gomina Amosun gẹgẹ bi
ojiṣẹ kan pataki ti Ọlọrun ran wa saye lati fi itura si igbe aye awọn mẹkunnu.
Sọrọsọrọ ori rẹdio ti wọn fi ami ẹyẹ Dokita da lọla niluu Ibadan, ni awọn iṣẹ
akanṣe idagbasoke Amosun ṣẹ afihan rẹ gẹgẹ bi olotitọ ti kii yẹ adẹhun rẹ to ba
ṣe.
Amosun ko sai dupẹ lọwọ Ọlọrun
fun idasi ati alaafia. Bakan naa lo dupẹ lọwọ ẹbi ati awọn alajọṣiṣẹ pọ rẹ fun
atilẹyin wọn ati ifọmọniyan ṣe.
0 comments:
Post a Comment