*Adetunji
n’Ifa gomina Ọyọ mu gẹgẹ bi ọba tuntun
*Oyediji ko 170, 000 le ọba Odulana lọwọ lati gba igbega
oye
*Iṣẹṣe n ta kangbọn pẹlu iwe ofin niwaju adajọ kootu
Gomina Abioa Ajimobi |
Rugudu
to ti bẹsilẹ lẹyin ipapoda Ọba Odulana Odugade
nipa oye ọba tuntun tun ti gbinaya pẹlu bi gomina Ajimobi ṣe tako Oloye Adebayo
Oyediji to jẹ mọgaji idile Seriki tilẹ Ibadan.
Ninu
ọrọ Ajimobi niluu Abuja, lẹyin to tufọ Ọba Samuel Odulana Odugade fun Aarẹ
Muhammadu Buhari lọjọ Iṣẹgun to kọja yii, lo sọ fun awọn oniroyin wi pe, Adebayo Oyediji kọ ni ipo ọba Olubadan
tọ si nitori eto ti wa nilẹ ti kosi ruju rara.
Oloye Oyediji lati idile Seriki lo n wi pe, oun ni ipo ọba Olubadan
kan lẹyin ipapoda ọba Odulana yatọ si Oloye Saliu Akanmu Adetunji ti awọn igbimọ
n ti lẹyin gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ Olubadan tuntun.
“Oyediji
ti n wi pe oun ni oye ọba Olubadan kan, to ba tilẹ jẹ wi pe Sẹriki ni oye rẹ, eleyii ti ko tilẹ ti i rijẹ,
oye to le kan an lẹyin oye Seriki ni Ẹkẹrin. Ẹnikẹni ko le fo lati Sẹriki de
ipo Olubadan, ko ṣeeṣe.” Ajimobi ṣe lalaye bẹẹ
Bi
gomina Ajimobi ṣe n sọ bayii ni ilu Abuja, lọwọ kan naa ni Oloye Oyediji n da a
lohun nikete ti iroyin naa kan an lara niluu Ibadan. To si n da a pada wi pe, “ko
ba dara ti gomina ba le yago fun ọrọ ti wọn ko ba gbe de iwaju rẹ. Nitori ọrọ
oye ọba Olubadan ti de iwaju kootu,” Oyediji fun lesi pada bẹẹ.
Oloye Oyediji tun fi kun
un ninu awọn alaye rẹ kan to ṣe wi pe, odindi ẹgbẹrun lọna adọsan owo naira ilẹ
Naijeria (N170, 000) ni oun ko le Oba Odulana to gbesẹ lọwọ nitori ki won le
fun ni igbega lati Osi Sẹriki bọ si Ọtun Sẹriki lọdun 2007, sugbọn ti igbega
naa kọ ti ko waye.
Ninu
iwe ipẹjọ Oloye Oyediji, eleyii ti agbẹjọro rẹ, A.G. Adeniran gbe siwaju ile ẹjọ
to gajulọ niluu Ibadan l’Ọjọbọ to koja yii (28/01/16), nibẹ ni won ti n sọ wi
pe, awọn igbimọ Olubadan tapa si abajade ile ẹjọ ọdun
1989. Abajade ile ẹjọ ọdun 1989 yii lo paṣẹ fun awọn igbimọ Olubadan lati mu Sẹriki
mọra gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ Olubadan eleyii ti yoo fun ni anfaani lati jẹ
ọkan lara awọn ti n jẹ oye ọba Olubadan.
Ninu awijare agbẹjọro naa lo ti n wi
pe, “awọn igbimọ Olubadan tapa si abajade ọdun 1989 to fi jẹ wi pe, won ko faye
gba Oloye Adisa Meredith Akinloye, to jẹ Sẹriki to jẹ kẹyin, lati darapọ mọ
igbimọ Olubadan”. Gẹgẹ bi alaye rẹ, o ni
idajọ ile ẹjọ ọdun naa lo sọ ilana oye jijẹ ilu Ibadan di ilana mẹta eleyii ti
awọn igbimọ naa foju parẹ.
Gẹgẹ bi alaye Ọgbeni Michael Lana, agbẹjọro ti n
soju fun awọn igbimọ Olubadan, Ọgbẹni Lana rọ ile ẹjọ naa lati fun ni akoko diẹ
sii lati ṣe ayẹwo ati iwadii ẹjọ to wa lọwọ rẹ. O ni awọn onibara oun ṣẹṣẹ gbe ẹjọ
naa le oun lọwọ ni, o ni oun si niilo akoko diẹ sii lati mọ ibi ti oun yoo tọwọ
bọ lori iṣẹ tuntun ti wọn gbe le oun lọwọ naa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe agbẹjọro Adeniran
tako akẹgbẹ rẹ lori wi pe ki ile ẹjọ fun un ni akoko diẹ lori ẹjọ naa, sibẹsibẹ, onidajọ Muktar Abimbola gba ẹbẹ ọgbẹni Lana. Bayii ni ile ẹjọ sun igbẹjọ
naa siwaju di ọjọ kerindinlogun osu keji odun yii (16/02/16).
Ninu ọrọ ọgbeni Adeniran ti n gbẹjọ ro fun Oloye Oyediji, o ni
bi igba ti wọn foju idajọ ododo wọlẹ ni bi wọn ṣe sun igbẹjọ naa siwaju nitori
wi pe, otitọ ti foju han ko ja iye meji
Ṣugbọn ṣa, awọn igbimọ Olubadan ko ti yi ipinnu
wọn pada lori wi pe, Oloye Saliu Adetunji ni yoo jẹ oye Olubadan tuntun. Bakan
naa ni gomina ipinle Ọyọ, ẹni to dakẹ lori ọrọ naa tẹlẹ, ti pada fi ero rẹ han
nipa ẹni ti Ifa rẹ faramọ gẹgẹ bi ọba tuntun.
0 comments:
Post a Comment