Saliu Akanmu Adetunji |
*Won ti dajo iwuye Adetunji gege bi
Olubadan tuntun
Gege bi oro awon Yoruba to
wi pe, ti oba kan ko ba ku, oba mi ki i je. Eleyii ni awon igbimo Olubadan tile
Ibadan tele pelu bi won se da ojo tuntun ti won yoo fi oba tuntun je leyin
ipapoda Oba Samuel Odulana Odugade to waja lojo kokandinlogun osu kinni odun
yii (19/01/16).
Nibayii, gbogbo eto ti to,
ojo kerin osu keta odun yii (04/03/16) ni won da lati jawe oye Oba Olubadan le
Oloye Saliu Akanmu Adetunji lori gege bi Olubadan tuntun.
Igbese tuntun yii lo waye
leyin ti ile ejo da Oloye Adebayo Oyediji lebi lori ipejo to gbe si iwaju ile
ejo lati da eto ifinijoye naa duro. Saaju akoko yii ni idile seriki ti Oloye
Oyediji n se olori fun gba iwaju adajo Mukhtar Abimbola lo pelu esun wi pe, awon
igbimo olubadan ko leto lati fi oba tuntun je nigba ti ejo si wa lori eni to ye
lati joba ni kootu. Sebi won ni tigi ba relugi, toke re la a ko re kuro.
Awuyewuye ti won te pepe
re siwaju ile ejo naa ni eyi ti olori
idile seriki, Oloye Oyediji, ti n so wi pe, oun loye lati je Oba Olubadan. Ejo
naa si ti de ile ejo eleyii ti ko ti niyanju titi di asiko yii. Sugbon ni akoko
ti eyi n lo lowo, ni awon igbimo Olubadan n so wi pe, jije oye Olubadan ko ruju,
“Balogun Olubadan ti n se Oloye Saliu lokan lati joba. Kosi si ohunkohun to le
di wa lowo lati ma se ohun to ye. Eni ti inu re ko ba dun si i le gbejo lo si
kootu ijoba,” awon igbimo fenu ko bee.
Sugbon sa, gbogbo atotonu
amofin-agbejoro Abideen Adeniran ti n soju idile seriki lati ma je ki eto oba
jije naa waye lo ja si pabo nigba ti adajo agba ti n joko nile ejo to gaju nile
Ibadan, Onidajo Mukhtar Abimbola da ejo naa nu gege bi ejo ti ko lese nile
rara.
0 comments:
Post a Comment