*Won ni ki won yegi fun un
leyin to pa omo ijo re
Opin irin ajo ti de
ba Rev. Chukwuemeka Ezeugo ti inagije re
n je Reverend King nigba ti ile ejo to gaju yan-anyan, Supreme Court, tun fi
onte lu u wi pe ki won lo yegi fun titi ti emi yoo fi jade lara re. Oludari ijo
Christian Praying Assembly to kale siluu Eko ni ile ejo kotemilorun ti koko fi
ontelu ejo ti ile ejo kootu ti da tele wi pe ki won yegi fun Rev King pelu bo
se seku pa okan ninu awon omo ijo re, Ann Uzoh, ni ojo keji osu kejo odun 2006.
Oluso-agutan ti won pe ni
Rev. King yii lo dana sun awon omo ijo re meje (7) kan latari wi pe o fi esun
pansaga kan won. Ninu awon meje ti Rev King dana sun bi eran ileya ni Ann ti
rekoja lo sorun aremabo.
Ejo ti won ti koko da lojo
kerinla osu kinni odun 2007 wi pe, iku lere ese owo Rev. King. Sugbon maanu naa
tun pejo kotemilorun lori ejo ti won da naa.
Nile ejo kotemilorun, ika
eniyan kan ko ni lo lai jeya to to labe ofin ni adajo tun ko lorin seti Rev
King.
Leyin eyi ni Rev. King tun
fo fere lo si ile ejo Supreme to wa niluu Abuja boya Ifa won yoo fore yato si
ejo ti won ti n da seyin.
Sugbon ibi pelebe naa ni
abebe ti won so soke niluu Abuja tun fi n lele. Adajo ni ki won lo yegi fun un titi
ti emi yoo fi jade lara Rev. Chukwuemeka Ezeugo ti gbogbo eniyan mo si Rev.
King.
0 comments:
Post a Comment