Ogbeni Samuel Omosaba, eni
odun mejilelogoji (42), ni owo awon olopaa
ipinle Ondo ti te bayii pelu bo se ge ori omobirin, eni odun meta (3),
to je omo aburo re lati fi sogun owo ojiji. Isele yii lo waye ni agboole Ilepa
to wa ni Ikare-Akoko ni ijoba ibile Ila-oorun Ariwa Akoko tipinle Ondo.
Ogbeni Omosaba ti ko nise kankan
ti n se lo ledi apopo pelu babalawo kan to kale si Ipe-Akoko, eni to seleri
lati ba a se ogun owo ojiji to daju to ba le wa
ori omode wa.
Omobirin ti won seku pa
yii ni iya re, ti n je Bunmi, maa n mu lo sodo iya oko re nigba to ba n lo sibi
ise laaaro. Sugbon lojo ti isele buruku yii yoo sele, ko si iya oko re nile,
egbon oko re lo ba nile. Egbon oko re naa lo gba omo naa sodo lati toju titi ti
iya re yoo fi pada de.
Igba ti iya omo yo pada
de, to silekun yara egbon oko re, lo ba oku omo re ti won ti ge ori kuro lorun
re. Ogbeni Omosaba pada jewo fun awon ebi nipa bi o se fe fi omo naa gunse owo.
Ogbeni Femi Joseph to je
agbenuso fun ile ise olopaa ipinle Ondo ni awon eniyan adugbo naa ko ba ti dana
sun Ogbeni Omosaba ti ki i ba ki i se iranlowo awon olopaa. Bakan naa lo tun so
wi pe, won ti gbe ejo naa lo si eka ile ise olopaa ti n risi idaran (State
Criminal Investigative Department), to wa niluu
Akure.
0 comments:
Post a Comment