“Ilaji owo osu won nijoba
yoo ma yo fi san gbese naa” -Komisanna isuna owo
Gomina Ayodele Fayose ti yanda
owo to le ni igba milionu owo naira (N236,860,000) gege bi owo ti won ya soto
lati ya awon osise ipinle Ekiti lati fi ra orisii moto to ba wu won.
Komisanna eto isuna ipinle
Ekiti, Toyin Ojo, so wi pe, awon osise ti anfaani naa si sile fun yoo ni
anfaani lati ya owo to to egberun lona ogorin (N80,000) si milionu kan abo (N1.5m),
eleyii ti won yoo tewo gba lodindi.
Komisanna tun so siwaju wi
pe, ki i se gbogbo osise ni o leto si anfaani yii bikose awon kan ti won ti n
sise siru ilu fun awon akoko kan ati ipo won lenu ise ijoba.
Lara afikun komisanna ni
wi pe, awon osise ti won ba setan lati je anfaani yii ni lati fara mo ilana ati
agbekale to wi pe, ilaji owo osu won ni ijoba yoo ma yo lati fi kase gbese naa
nile. Bakan naa lo tun fi n da awon osise to ku loju wi pe, laipe, anfaani
owoya lati fi ra moto ara eni yoo kari gbogbo won pa.
0 comments:
Post a Comment