*Femi Adebayo n wonu oselu lo diedie
Nibayii,
gomina ipinle Kwara, Abdulfatah Ahmed, ti yan ogbontarigi onisetiata, Femi
Adebayo, gege bi oluranlowo pataki nipa ise ona, asa ati irinajo-afe (Special
Assistant on Arts, Culture and Tourism). Osere ti inagije re tun je Jelili ko
le pa ayo naa mora pelu bo se kede iyansipo re naa lori ayelujara fun awon
ololufe re pata.
Bakan naa lo tun un dupe lowo gomina ipinle Kwara fun anfaani
ti won fun un lati kopa ninu idagbasoke ipinle Kwara. Igbese tuntun yii ni awon
kan ri gege bi ategun fun osere naa lati ridi joko ninu oselu ipinle re. Eleyii
ti won lo se e se ko fun ni koriya lati gbe apoti idibo ninu eto idibo ojo iwaju.
0 comments:
Post a Comment