*Oba Ogunwusi n mura lati
se igbeyawo tuntun
Lose to koja ni awon aheso
oro kan be sile nigboro eleyii to ti bere si ni mu awuyewuye lowo bayii. Lara
awon oro naa ni eyi ti n wi pe, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi ti ko aya re,
Olori Adebukola Ogunwusi sile. Ede-aiyede to be sile laaarin loko-laya naa lo
tun pada bureke leyin ti won jawe oye le Oba Ogunwusi lori.
Bi o tile je wi pe
gbagbaagba ni Olori Bukola le mo Oba Ogunwusi lojo ti Gomina Aregbe gbe opa ase
le e lowo, sibesibe, ohun ti a gbo ni wi pe, ikunsinu ti be sile laaarin
ololufe meji naa saaju akoko naa. Wahala to wa laaarin loko-laya yii ni idile
mejeeji si ti gbiyanju ki won pari sugbon ti gbogbo akitiyan naa jasi otubante,
ofo ojo keji oja.
Gege bi akiyesi awon
eniyan, won ni lati igba ti won ti bura fun Oba Ogunwusi ni won ko ti ri i pelu
aya re mo, eleyii to mu ifura dani wi pe, oseese ki awon aheso oro naa ni otito
ninu.
Nibayii, omobirin tuntun
ti won lo se e se ko je aya oba tuntun laaafin ni Omidan Wuraola Otiti Zynab
Obanor to wa lati agboole Oluyare to wa ni adugbo Iremo ni ilu Ile-Ife.
Sugbon sa, ilu Benin ni
iran awon omo naa ti se wa si ilu Ile-Ife. Omidan Wuraola mole gboo bi ojo, awo
ara re si tutu minijojo bi eja arogidigba lodo. Ewa omidan naa lekenka to bee
gee, eleyii ti opo awon eniyan gba wi pe yoo tun bu iyi kun Ooni Ojaja gege bi
oba to gbo faari oge sise.
0 comments:
Post a Comment