Smiley face

Ewon odun merinla (14) n run lori Saraki to ba jebi esun CCT


Bukola Saraki
Awon agbaoje onimo ofin ile Naijiria ti salaye fun awon oniroyin wi pe, oseese ki Bukola Saraki padanu ipo re gege bi aare ile igbimo asofin agba pelu ewon odun merinla (14) to ba pada jebi esun ti won fi kan an. Saraki ni ile ejo tiribuna CCT fesun metala (13) kan eleyii ti aisododo nipa iye dukia re nigba to wa nipo gege bi gomina ipinle Kwara je okan pataki nibe. 


Ile ejo tiribuna yii ni Saraki ti gbe de iwaju ile ejo to gaju patapata nile yii, nibi to ti n ro ile ejo naa lati si ile ejo tiribuna lowo ise lori awon esun ti won fi kan an naa. Sugbon leyin gbogbo ilakaka Saraki lati ri oju rere ile ejo to gaju, pabo naa ni akitiyan Saraki jasi nigba ti ile ijo to gaju nile yii tun bo fun tiribuna lagbara lati tesiwaju ninu ise won. Ile ejo to gaju tun se alaye abala ofin to faaye gba CCT lati fesun kan oniruuru asoju ijoba ti aje ibaje naa ba si mo lori.

Lori oro yii kan naa ni awon omoran ti won moyun inu igbin nipa imo ofin ti bere si ni tu inu iwe ofin ile Naijira lati mo orisii ijiya to to si eni to ba se si iru esun ti won fi kan Saraki.
  
Gege bi iwe ofin ile Naijiria ori ketalelogun (Section 23) abala kinni ati abala keji se so.
Ni abe ofin naa ni won ti n so wi pe, eni to ba jebi iru esun ti won fi kan Saraki yoo lo si ewon odun merinla (14) pelu ise asekara leyin to ba padanu ipo re. Bakan naa ni eni naa ko ni ni anfaani lati ni ibase pelu ohunkohun to nii se pelu eto ilu fun odun mewaa gbako.

Sugbon sa, awon omo ile igbimo asofin agba, eleyii ti pupo won je awon omo egbe PDP, ni gbagbagba ni awon si wa leyin Saraki, eni to ti fi igba kan je omo egbe PDP ko to bo sinu egbe APC.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment