*Awon ole afobanki sagbako n’Ikirun
Meji ninu awon igara olosa
ti won fo banki meji papo leekan soso ni agbegbe Ikirun ni ipinle Osun ti koja
sorun aremabo nigba ti bajinatu awon agbofinro dun lara won. Ni ojo Eti to koja
yii (12/02/16) ni awon adigunjale naa yabo ile ifowopamo First Bank ati Skye to
wa n’Ikirun leekan soso pelu awon agbelero bombu ti won fi fo enu ona awon
banki naa wole.
Gege bi alaye to te Olayemi Oniroyin lowo, awon osise banki Skye
meji ni won se agbako iku latari ado oloro agbelero ti awon ole naa fi n fo
awon enu iloro ile ifowopamo naa ni akoko ti won gbiyanju lati wole si won
lara.
Sugbon gege bi oro awon
agba, ojo gbogbo ni tole, ojo kan pere ni toloun. Nibi awon ole yii ti gbe n
palemo owo ti won ko sise fun ni awon olopaa ti won dira ogun ti gbe kan won
lara lojiji. Bayii ni eruku ibon pau-pau se bere si ni ta lala laaarin awon
olopaa ati awon adigunjale. Ninu itaporogan to sele fun odindin wakati kan ni awon
olopaa ti gbe gba emi awon ole meji nigba ti won si ri meji mu laaye ninu
won.
Alarina fun ile ise olopaa ipinle
Osun, DSP Folashade Odoro, je ri si isele naa wi pe, lotito ni ile ise olopaa
mu ole meji bale nigba ti owo te awon meji mi i laaye. Bakan naa ni arabirin
naa fi kun wi pe, okan ninu awon meji ti won mu laaye ni ibon ti ba, eleyii to
si n japoro titi di akoko akojopo iroyin yii.
0 comments:
Post a Comment