Opolopo wa ni a n lo foonu
ni aye ode oni, sugbon ti a kosi mo awon ewu keekeke to ro mo o eleyii to le se
ipalara fun ago ara wa.
E je ka ri daju wi pe a n
nu foonu wa lorekoore. Paapaa julo, ti a ba lo foonu wa ni akoko ti a ba n
laagun pupo. Orisiirisii kokoro aifojuri lo le jeyo latari aagun to gbe mo ara
foonu wa eleyii ti a tun pada gbe seti. Bakan naa, awa ti a ni omo ikoko nile,
e ma je ki awon omo wa maa fi foonu wa sere debi wi pe, won yoo ma ponla lati
fi senu.
Ewu nla wa ninu ki foonu
maa gba agbara lowo ni akoko ti a ti bona, ki a tun ma wa fi iru foonu bee pe
lai yo kuro ninu ina. Ti a ba n saaji foonu wa lowo, ti ipe ba wole, e je ki a
yo kuro ninu ina ki a to gbe ipe naa.
Awon kan tun feran lati
maa fi earpiece seti sun lo, awon nnkan bayii lewu. E si je ka yago fun opolopo
ariwo to le se akoba fun eti wa ni akoko ti ba n lo earpiece lati gbo orin.
Awon kan tile so wi pe, ka maa lo earpiece eleti kan dara ju eleti meji lo.
Eleyii yoo fun yin laaye lati gbo ohun ti aye so ni akoko ti e gbo orin lowo.
A ti wi pe, ti eti kan ba
ti n ta yin, e le paaro si eti keji. Pupo ninu awon iyaloja
feran ki won maa fi foonu pamo si aarin palapolo igbaaya won. Asa bayii ko
dara, o lewu fun ilera. Ti e ba fi foonu si igbaaya ti ipe ba wole, ti foonu
naa ba wa ni gbigbonriri (vibration), o le se akoba fun okan yin.
E si je ka soro nipa gbigbe foonu saya sun lo
tabi didaya le foonu sun mole.
Awon iwadii oke yii la se lati owo
awon osise alaabo ilera, yoo si se yin lanfaani ti e ba le samulo re gege boti
ye. Alafia wa ko ni di fiafia. Amin.
0 comments:
Post a Comment