Smiley face

Faleke n leri leyin ti won fi Achuba je igbakeji gomina



 *“Gomina ‘illegal’ ti ko lese nile lo wa nipinle Kogi”- Faleke
*Omo Igala ti gba eto omo Yoruba (Okun) ni Kogi
*Ojukokoro le sakoba fun Faleke” Itakuroso ori intaneeti
 
Achuba nigba ti won bura fun gege bi igbakeji gomina
Ogbeni James Abiodun Faleke ti se alaye gomina Ipinle Kogi, Yahaya Bello, gege bi gomina ti ko lese nile labe ofin eleyii to fi han wi pe, ofutufete lasan ni gbogbo igbese re pata. Alaye yii lo jade leyin ti Gomina Yahaya Bello yan Ogbeni Simon Achuba gege bi igbakeji gomina lati fi ropo Faleke to kojale lati je igbakeji re.


Ninu oro Duro Mesoko to je adari eto iroyin fun Audu/Faleke Campaign Organisation, to tun un gbenuso fun Falake so wi pe, gomina ti ko lese nile labe ofin, gbogbo eni yoowu kori ko yan sipo naa ko le lese nile rara.


"Mimi kan ko mi wa. Opin irin ajo ko ni pe de si gomina ‘illegal’ ti ko lese nile to tun yan igbakeji gomina ti ko lese nile. Idi ni yii ta a fi gbe ejo wa dewaju tiribuna nibi taa ti da sile ta tun gbe tun sa bi igba ti adie ibile ba n sa yangan. Faleke lo ye loye gege bi gomina, ni agbara Olorun to da oke ati ile, olododo ko ni ku sipo ika laelale. Ifa Faleke ni yoo leke ti yoo si gba gbogbo eto re pada ti ko ni ku woro kan lowo awon olote," Mesoko se alaye re bee.


Saaju akoko yii, Faleke ti bere si ni ju oko oro si Oloye John Oyegun, alaga egbe APC lapapo gege bi agbalagba ti n sabosi.

"O se ni laanu wi pe awon agba to ye ki won tun nnkan se ni won tun ka modi ibaje. Iru awon agba bayii ko si ye lati di ipo alaga egbe APC mu," Faleke juko oro bee si  Oloye Oyegun.
 
Faleke n wonu ile igbimo asoju-sofin lo niluu Abuja
Sugbon ninu awon oro Oloye John Oyegun, lo ti n so wi pe, enikeni ko ga ju egbe lo; egbe lo ga ju. Anfaani egbe si gbodo saaju anfaani yoowu ti enikeni le ma wa nidi oselu. Oyegun tun so wi pe, bi awon ko ba gbe igbese ti awon gbe, anfaani ni yoo je fun egbe alatako lati ja ipo gomina naa gba mo egbe APC lowo ti gbogbo re ba pada jasi oro kootu leyinoreyin.

Lose to koja yii ni won bura fun  Simon Achuba gege bi igbakeji gomina nipinle Kogi lati fi ropo Faleke. Achuba lo ti fi igba meji seyin je omo ile igbimo asofin ipinle naa, igbakeji re ti yoo pada sile lo ni anfaani lati je igbakeji olori ile igbimo asofin ipinle naa.

Ogbeni Achuba ti won ti bura fun gege bi igbakeji gomina yii lo wa lati ijoba ibile Ibaji eleyii to n se ara eya Igala to wa ni ipinle Kogi. Igbese tuntun yii lo si mu iran awon omo Yoruba ti a mo si Okun ti won wa ni Ipinle Kogi padanu ipo naa. Ipo kan naa yii ni won ti fi n be Ogbeni Faleke to wa lati ijoba ibile Ijumu to je okan lara agbegbe Okun ti n se iran Yoruba to kale si ipinle naa. Leyin iyansipo Achuba gege bi igbakeji yii ni opo awon eniyan ti bere si fi ero won han lori ayelujara. Awon kan ni ojukokoro lo pada sakogba fun Faleke bi igbakeji gomina se bo mo o lowo. Won ni ti maanu naa ko ba si mura, afaimo ki awo re ma sun lebi. 

Eleyii to fi n je wi pe, ofo ojo keji oja loro re yoo pada jasi. Lori ero ayelujara ti awon kan ti n yo aseju Faleke le e lowo, ni awon kan ti n gbe sadankata-o-kare-okunrin-ogun le e lejika. Won ni, iyanje nla gbaa ni bi won se gbe ipo gomina naa fun eni ti ko ba won foju wina ipolongo ati eto idibo to wa pada je gomina.  Awon nnkan wonyii ni awon kan si n salaye gege bi ipo ti oselu ile wa wa, eleyii ti won ni ko kare to.

 
Nibayii ti Faleke ti fi ireti re si iwaju ile ejo tiribuna, oro re ti wa dabi ode ti n renugbo. Bakan meji si loro ode ti n renugbo lo re e peran; o le reran pa, o si le ma reran pa. Sugbon ti Faleke ko ba reran pa, ki ni yoo je ipin re? Ibo lo fe gboju si niwaju awon eniyan re nipa anfaani won to bo somi? Ipade di kootu tirubuna, niwaju adajo ti n gbo awuyewuye to suyo leyin idibo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment