*Aare Buhari ko dasoro omo
Owu at’Obanta
"Mi o ni faramo idasile ipinle Ijebu ayafi ti won ba gba lati je ki olu ipinle naa wa ni Ikenne," oro yii ni aare orileede yii nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo n so lati fi fesi pada si oro ti Awujale tile Ijebu, Oba Sikiru Adetona so saaju. Nibi apero ti won se nibi ayeye ogoji odun (40th) ti won da ipinle Ogun sile ni Awujale ti n pe fun iranlowo ati atileyin Ebora tilu Owu, Aremu baba Iyabo nigba to n fi ero re han niwaju Aare Muhammadu Buhari.
Ilakaka idasile ipinle Ijebu
lo ti wa nile fun igba pipe, eleyii ti ijoba apapo ko kobiara si. Oba Sikiru
tun lo anfaani ayeye ogoji odun ti won da ipinle Ogun sile naa, nipa wiwa oju
rere ijoba apapo nipa idasile ipinle
Ijebu.
Ninu oro Obasanjo, to tun
je sanko ninu awon to gbogun ti iyansipo Goodluck Janathan fun igbakeji, so wi
pe, oun setan lati se atileyin fun iwasaye ipinle Ijebu sugbon olu ilu naa
gbodo wa ni ikenne.
“Mo setan lati se atileyin
fun idasile Ijebu, ti won ba gba lati je ki olu ipinle naa wa ni Ikenne to je
orirun premier ti Western Region nigba kan ri, Oloye Obafemi Awolowo,” Obasanjo
fesi bee pada.
Awon oro agba meji lati
ipinle Ogun yii ni awon onwoye lagbo oselu ti bere si ni tanna wo lati mo
kilo-bayii-wa. Won ni niwon igba to je wi pe, oba ti n je n’Ijebu-ode naa lo fe
e je asaaju oba alaye fun gbogbo ile Ijebu, won ni iru nnkan baayii le ma fun Awujale
ni ifokanbale wi pe, Ijebu-ode ni yo fe e je olu ilu ipinle tuntun naa ti won
ba da a sile tan. Won ni, idi ni yii ti oba alaye naa ko fi jawo lori e-fun-wa-nipinle-Ijebu
to ti n ran an menu fun aimoye odun seyin.
Sugbon nipa ti Obasanjo,
sebi awon agba naa ni won wi pe, ti awo ba ku, awo ni i selede leyin awo. Gege
bi oloselu pataki asiko yii, Obsanjo mo riri ise oselu takuntakun ti Obafemi
Awolowo baba Ikenne se nigba tie. Won ni idi ni yii to fi n ja fun ohun to le
duro bi aponle fun oku orun.
Nibi ipade naa, Buhari ko
tile soro le ohun to niise pelu idasile ipinle Ijebu ti Obasanjo ati Awujale jo
fi n bara won tayo olopon. Bikose ifaseyin to de ba oro aje nipase epo robi.
Bakan naa ni Buhari fi igba ti Obasanjo fi je minisita fun epo robi we ipo ti
epo robi Naijiria wa bayii.
Sugbon sa, gege bi awon
onwoye nipa oro oselu se so, won ni oseese ki idasile ipinle Ijebu ya kiakia ti
Awujale ba le faramo aba Obasanjo. Sugbon ti Awujale ba se bee, bi igba to sise
fun omo elomii je ni. Eleyii ti ko si daju wi pe omo Obanta yoo gba si omo Owu
lenu.
0 comments:
Post a Comment