“$1m ni Buhari maa na lo irin ajo kan siluu
Okeere” Fayose
Gomina Ayodele Fayose ti
fi waasu re ranse si aare orileede Naijiria, Muhammadu Buhari, lati jawo nipa
wiwa iranlowo lo si awon ilu Okeere. Ninu oro Fayose, eleyii ti oluranlowo re
nipa oro to n lo ati iroyin ayelujara, Lere Olayinka, gbe sita ni Ado Ekiti, ni
Fayose ti n wi pe, eleru ni yoo koko gbe eru re nibi to gbe wuwo.
Fayose tun tesiwaju ninu alaye re wi pe, irinajo Aare Buhari n se ipalara nla fun eto oro aje wa. Nitori o kere tan, ijoba apapo n na owo to to bi milionu dollar owo ile Amerika kan ($1m) lori irin-ajo kan pere. " Ti e ba si foju wo o, lati igba ti aare ti wole ni idi re ko ti joko nile to je wi pe n se ni fo kiri bi eye," Fayose tun tesiwaju ninu alaye re. "Pupo ninu awon irinajo aare si awon ilu okeere yii lo je wi pe, awon minisita le lo tabi igbakeji aare, eleyii ti o fun aare ni anfaani lati gbajumo awon isoro abele ti n yo wa lenu bi eto oro aje ati abo ilu to mehe nipa ogun Boko Haram," Fayose fi kun oro re bee.
Gomina Fayose tun se mo alaye re to fi ranse
si Buhari wi pe, ko ba dara ti aare ba n teti si oro enu oun eleyii to jo bi
atako leti Buhari sugbon to kun fun ogbon ati anfaani to po repete. O ni awon
ti won yin Buhari ko ni anfanani kankan ti won fe se fun ijoba re tori ohun ti
won yoo ponla ni gbogbo won wa.
0 comments:
Post a Comment