*Idajo esekese fun awon to
ba rufin oju popo
*Asiko ni yii fun awon
olokada ati danfo lati satunse
Kootu alagbeka Ambode |
Gomina Akinwunmi Ambode
tun gbe ara otun wo ipinle Eko wa pelu bi ijoba re se se ifilole kootu alagbeka
lati gbogun ti awon ti won rufin oju popona. Ojo Eti (05/02/16) to koja yii ni
ijoba ipinle Eko se ifilole kootu alagbeka naa eleyii ti won pe ni Special
Offences Mobile Court ninu ogba ile ejo to gaju lo ti ipinle Eko to kale si
Ikeja.
Nibi eto ifilole naa ni
komisanna fun eto idajo ti ipinle Eko, Ogbeni
Adeniji Kazeem ti so wi pe, ifilole kootu alagbeka naa je lara eto ijoba
Ambode lati feju ona ati tete ri idajo odo gba awon ara ilu ati lati mu asa
sise ohun gbogbo letoleto gege bo ti ye kesejari.
"Awon ohun ti a le so
wi pe o mu ijoba Ambode ji giri nipa sise iru eto yii ko ju awon olokada ti won
feran ki won ma doju ko ona ti moto n gba bo, awon danfo ti won si ilekun won sile
lori ere eleyii to mu emi awon eniyan wa ninu ewu. Bakan naa ni awon elese ti won
ko biriji sile laigba to je wi pe titi marose ni won feran ati maa sare gba
koja. Awon iwa bayii ko fi wa han gege bi awujo to ni asa titele eto gege bi agbekale
ilana," Ogbeni Kazeem se alaye naa bee.
Bakan naa ni komisanna tun
wi pe, awon awako ti won ba gba oju ona ti kii se ti won bi oju ona BRT naa ni won
yoo fika abamo hamu niwaju kootu alagbeka tuntun yii. Koda, komisanna tun menu
ba awon soja alagidi to ba rufin oju ona ko ni sai foju wina ofin idajo niwaju kootu alagbeka.
Gege bi alaye adajo agba
fun ipinle eko, Olufunmilayo Atilade, so
ninu alaye tie wi pe, eto tuntun yii yoo mu adiku ba emi awon eniyan ti awon ti
ko bikita ofin irinna n seku pa nigbogbo igba. Bakan naa ni onidaju agba Atilade
ko sai menu ba isele to seku pa Doyin Serah Fagbenro, eni odun meedogbon (25)
ti awako kan seku pa latari iwakuwa oju popona ni agbegbe Lekki-Ajah. O ni ti
ko ba si ilana a ti dekun iwa ibaje yii lawujo, ipalara re si awujo yoo tun bo
maa lekenka si i ni.
Awon kootu alagbeka yii ni
won gbe kale sinu oko bogini nla akero eleyii ti won yoo ma yipo ipinle Eko ka
lati se idajo awon arufin oju popo. Adajo majisireeti yoo maa tele awon kootu
alagbeka yii pelu awon agbejoro lati Office of the Public Defender (OPD). Awon agbejoro ti won yoo ma
tele kootu yii ni yoo wa fun arufin to
ba fe lati be won lowe niwaju adajo.
0 comments:
Post a Comment