Smiley face

"Ayanmo mi ni lati lo odun mejo lori oye"- Ajimobi



3:0 ni Ajimobi gba fun Ladoja ni kootu


Gbogbo akitiyan Rasheed Adewolu Ladoja lati gba ipo gomina ipinle Oyo pada lowo Gomina Abiola Ajimobi nile ejo ti pada jasi pabo patapata. Ladoja to ti n fapajanu nikete ti won ti kede esi idibo gomina ipinle naa to waye ninu osu kerin odun to koja yii, lo ti koko gbe ejo naa de iwaju ile ejo ti n gbo awuyewuye leyin eto idibo (Election Tribunal). 


Leyin ti won da Ajimobi lare ni Ladoja, to tun je Osi Olubadan, gba ile ejo ko-temi-lorun lo. Esun Ladoja naa si ni wi pe, makaruru, magomago, po ninu ibo to gbe Ajimobi wole si ile ijoba ipinle naa to wa ni Agodi, Ibadan.

Oro Ajimobi pelu Ladoja niwaju adajo dabi abebe eleyii ti n fi ibi pelebe lele nigbogbo ojo, bee gele lori pelu bi ile ejo kotemilorun tun se da Ajimobi lare. Ohun ti ile ejo wi naa ni wi pe, awon awijare Ladoja to je gomina ipinle Oyo nigba kan ri, ko lese nile rara.

Leyin eyi ni Ladoja, eni odun mokanlelaadorin (71) tun gbe Gomina Ajimobi, eni odun merindinlaadorin (66), lo si ile ejo to gaju nile yii (Supreme Court) lori esun kan naa. 
Igbejo yii lo waye lojo Isegun ose to koja yii nibi ti Ajimobi ti jajasegun niwaju ile ejo kootu to ga julo nile Naijiria. Eleyii ni yoo si maa se igba keta ti Ladoja yoo ma fidiremi lori akitiyan re lati gba ipo gomina pada.

“Mo n lo akoko yii lati ro omo iya mi, Senato Rasheed Ladoja, ati awon alatako yoku lati fowosowopo pelu wa lati gbe ipinle Oyo de ipele to lapere yato si ipo abule to wa. Mo dupe lowo awon eniyan ipinle Oyo fun iduro sinsin won. Aseyori yii, ti gbogbo wa ni. Ladoja ti n sunmo ipo oba Olubadan bayii. Ki won tile fi je Olubadan ko le jawo ninu awon ija oselu to wa maya. Ayanmo mi lati odo Oluwa ni lati lo odun mejo (8) lori oye gege bi gomina," oro Gomina Ajimobi ni yii leyin ti ile ejo gbe are fun un.

Ninu oro Ladoja, o ni asiko ni yii lati fi owo sowopo pelu ijoba to wa lode ki ipinle Oyo le tesiwaju leyin idajo kootu to ga ju lo.

 Ninu eto idibo gomina to waye lojo kokanla osu kerin odun to koja (11/04/16) ni Ajimobi (APC) ti jawe olubori pelu iye ibo 327,310. Nigba ti Ladoja (AP) ni 254,520; Akala (LP) ni 184,111; Folarin (PDP) ni 79,019; Makinde lati inu egbe oselu SDP si ni 54,740. Eto idibo yii lo si so Ajimobi di gomina akoko ti yoo wole fun igba keji ni ipinle Oyo lati igba ti won ti da ipinle naa sile lodun 1976.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment