Smiley face

AIT ti lo tuuba niwaju Tinubu leyin esun ibanilorukoje


Bola Tinubu

Asiwaju Ahmed Tinubu ti pinnu lati se aforijin fun ile ise telifisan AIT leyin ti won ti lo fenu gbole niwaju re.

Ile ise telisan yii ni won bere si ni se akanse afihan awon akojopo alaye kan nipa Tinubu lodun to koja, saaju eto idibo, ti won pe ni “Unmasking the Real Tinubu: The Lion of Bourdillon."

Ninu akojopo alaye yii ni won ti se alaye Tinubu bi alanikanjopon, wobia ati eni to ko gbogbo oro-aje ilu sabe. Ile ise telifisan naa tile so wi pe, Tinubu ni lanloodu to ni dukia ju lo nipinle Eko.

Won se awon eleyii nipa sise afihan awon dukia bi ilegbee, ile itaja, gbongan nla, papa, ati awon agbegbe lorisiirisii ti won lo je ti gomina ipinle Eko nigba kan ri.

Lara alaye won lo tu wi pe, Tinubu ti figba kan foju wina ofin niluu okeere lori esun to ni i se pelu ogun oloro.

Nibi akojopo akanse iroyin alalaye ti won se, ni won ti se apejuwe okan pataki ninu awon oloye agba egbe APC gege bi mujemuje ti n mu gbogbo adun oro-aje ipinle Eko lojo gbogbo.

Afihan naa ba Tinubu lokan je, eleyii to si ko leta si telifisan naa lati jawo ninu iwa ibanilorukoje ti won rawo le. Sugbon kaka ko san lara iya aje, abo lo tun fomo inu re bi. Ile ise telifisan naa kotiikun si leta Jagaban ilu Eko. Won tesiwaju lati maa se afihan fidio naa lori telifisan won.


Leyin eyi ni Tinubu gbe ejo naa lo sile ejo pelu esun ibanilorukoje lojo karun-un osu keta odun to koja (05/03/15).

Ninu esun ti awon agbejoro fun Tinubu, Wole Olanipekun ati Tunji Abayomi pe ni won ti n beere fun owo itanran to je aadojo bilion owo naira ile wa (N150B) nipa bi telifisan naa se paro faye lati ba oruko Tinubu je.

Ni akoko ipejo yii ni onidajo Iyabo Akinkugbe ti pase fun telifisan naa lati da afihan akojopo iroyin won nipa Tinuba naa duro.

Sugbon gege bi oro awon agba, won ni teeyan ba bu oba leyin, ti eni naa ba dewaju oba to ba ni beeko lo ri. Awon agba ni, a gba wi pe eni naa ko bu oba rara ni.

Ati wi pe, enu tigbin ba fi borisa, nikete to ba ti fenu naa gbole loro buse. Ohun ti agbo ni wi pe, awon alase telifisan naa ti lo na felefele niwaju Tinubu lati toro aforijin asemase to towo won jade.

Gege bi oro awon Yoruba, won ni taa ba fowo otun bomo wi, o ye ka tun fi tosi faa mora. Eleyii ni Oloye Tinubu se gege bi agba ti n gba ohun gbogbo mora to si se bee darijin won patapata.

Igbese yii lo bi eyi to sele ni kootu lojo karun-un osu keji odun yii. Nibi ti agbejoro fun ile ise telifisan AIT, Mike Ozekhome ati agbejoro Oloye Tinubu, Wole Olanipekun, gbe duro niwaju adajo ti awon mejeeji si fohun sokan wi pe ki adajo kootu gboju kuro ninu ipejo naa.

"A ti tese ile bo oro naa, a ti lo yanju re ni tubinnubi, yoo si wu wa ki ile ejo ya faili ejo naa danu nitori wi pe ko sejo mo."

Bi Ogbeni Ozekhome to je agbejoro telifisan AIT se n so bayii, bee naa ni ogbeni Olanipekun naa gba lenu re to si n wi pe:
"Oluwa mi, ajebi ma mo lo kogun jalu, niwon igba ti elebi ba ti mo ebi re lebi. Ti eni oro kan si ti se idarijin fun-un, emi naa ro ile ejo yii lati paju faili ejo naa de titi ayeraye."

Onidajo naa gba alaye won wole. Bakan naa lo si pase fun ile ise telifisan naa lati bere si ni toro idarijin lowo Tinubu lori telifisan, o kere tan, eemeta lojumo.

Ki won si tun salaye fun ara ilu pe, isokuso ti ko lese nile gbaa ni gbogbo alaye iro ti awon kojo lati ba oruko oko Oluremi Tinubu je.

Ti e ko ba gbagbe, Ogbeni Raymond Dokpesi to je alase ati oludasile telifisan naa ko ti jajabo lowo fitinati ajo EFCC lori esun bilionu meji ati milionu kan (N2.1b) owo Dasuki ti won lo ponla.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment