Mimiko ati Amaechi |
*Mimiko (PDP) ati Amaechi (APC): Ore atijo meji pade l’Akure
Minisita fun igbokegbodo
oko, Ogbeni Rotimi Amaechi se abewo si ipinle Ondo pelu awon igbimo re l’Ojobo
ose to koja yii lati foju wo bi ayipada rere se le deba awon oju popona to je
tijoba apapo. Abewo yii lo mu ore meji atijo tun pada nigba ti Gomina Ipinle
naa, Olusegun Mimiko gbalejo Amaechi, eni to ti fi igba kan je omo egbe PDP
tele.
Ninu abewo yii, bi Mimiko
se n gbe ebun fun Amaechi, bee naa lo ran an leti lati jise fun ijoba apapo
lori awon owo ti ipinle naa ti na lori atunse asepati awon ona ijoba apapo to wa
ni ipinle Ondo. Gomina Mimiko to pada sinu egbe PDP to ti wa tele lati inu egbe
Labour se alaye wi pe, bilionu mokanla owo naira ile Naijiria (N11b) ni awon na
lori ona naa eleyii ti ijoba apapo yoo si dapada fun ipinle Ondo.
Ki awon oro gomina Mimiko ma
ba dabi oro asodun lasan, komisanna fun ise ode tipinle Ondo, Onimo-ero Gboye
Adegbenro, gbe iwe funfun nla kan jade eleyii to kun fun akosile ise oju ona to
je ti ijoba apapo sugbon ti ipinle naa ti fi owo apo won tunse.
"Oju ona Ore si
Okitipupa je ise owo Mimiko. Bakan naa oju ona Oweo si Ikare ni Olorun ti gba
owo Iroko se ise ribiribi. Iyen nikan ko, oju ona Ajowa to fi de ibi ti ipinle
Ondo ati Kogi ti gbe paala ni Olusegun Mimiko ti gbe segun nipa ipase titi
oloda ti n yo kululubi bi opopo’Mecca, komisanna salaye bee niwaju Amaechi ati
awon igbimo re.
Bakan naa ni komisanna tun
salaye siwaju wi pe, ijoba Buhari yoo da owo ti awon fi se oju ona Itanla si
oju ona Ondo pada. Eyi to tun jo iru re ni owo ti ijoba ipinle Ondo na lori
ikorikita Ore to wa loju ona Benin si Shagamu, ni won ni ijoba apapo yoo ko le
ipinle Ondo lowo lodinindi. Onimo-ero Adegbenro tun so fun Amaechi wi pe, inu
awon yoo dun ti ijoba ba le da owo ti awon na lori ona Igbara si Oke, ati eyi
ti awon na si Ogbese to je abala oju ona Ilesa si Owo pada.
Gbogbo alaye won ni
Minisita ko sapo bi Gomina Mimiko se gbe ebun le e lowo. O si fi n da won loju
wi pe gbogbo to ba ye ni ijoba to wa loke yoo se lati ri daju wi pe anfaani
ijoba awaarawa kari gbogbo mekunnu pata.
0 comments:
Post a Comment