*“Jonathan ko N4.7b sile lati feru gba ibukun fun Fayose” Akowe
PDP
*“Ona eru lagba fi gbe Fayose wole”- Aluko
*Imule ore ogoji odun (40) ti da Fayose
Gbegede gbina lose to koja
nigba ti akowe egbe PDP nigba kan ri fun ipinle Ekiti, to tun je okan gboogi
lara awon alatileyin Gomina Ayodele Fayose nigba eto idibo gomina, Ogbeni Tope
Aluko, bere si ni tu asiri bi awon se fi ona eru jawe olubori ninu eto idibo to
gbe Fayose wole gege bi gomina ipinle naa.
Ninu alaye re, o ni aare ana,
Goodluck Jonathan gbe bilionu merin o le milionu meje owo naira (N4.7b) kale
fun Fayose pelu aimoye soja. Eleyii to duro fun iranwo lori awon ilana magomago
ti awon pinnu lati fi gba ijoba lowo alatako re to je Kayode Fayemi (APC).
Aluko ko sai salaye bi won
se n gbe awon oloye egbe APC pamo si awon ileewe alakobere kan ati awon ago
olopaa eleyii ti DPO ibe je imule awon ni akoko eto idibo naa. Bakan naa lo tun
so bi won se pin owo riba fun awon soja ajoji ti won ko wolu lati ba won lowo
sinu gbogbo ise dudu ti won se ni akoko idibo naa.
O tile tun salaye bi won se
fi awon soja kan sowo siwon lati ile Yibo, eleyii ti won se iranwo nipa bi
magomago idibo naa se kesejari. Awon eto magomago ibo yii lo si pada mu Fayose
leke tente bi igba ti won fi lori omi.
"Ore a ti bi ogoji odun (40yrs) seyin ni emi ati Fayose. Emi si tun ni alaga eto aabo fun igbimo ipolongo eto idibo re. Ijamba nla ni a fi ja awon eniyan Ekiti, nitori wi pe magomago la se lati gbe Fayose wole gege bi gomina yato si ife ara ilu. Aare ana si je Balogun leyin ogba to ko gbogbo ohun elo sile patapata. Eleyii to mu gbo ise dudu owo wa rorun lati mu Fayose bori. Sugbon odale ni Fayose, Fayose se ileri lati so mi di olowo otun re nikete to ba wole. Sugbon Fayose gbagbe mi leyin ti agbara de owo re," Aluko se e lalaye bee fun awon oniroyin niluu Abuja.
Gomina ipinle Ekiti,
Ogbeni Ayodele Peter Fayose naa fesi si gbogbo esun makaruru ti Aluko fi kan an
naa.
"Ohun to ba wu eye
Aluko lo le fi enu re ko lorin nipa iro ti n pa a kiri. Otito ni emi duro le,
otito ni yoo si leke ni gbogbo ojo. Awon eniyan kilo fun mi wi pe, ki n ma fi
Aluko se olowo otun mi (chief of staff). Nitori odale ati alagabagebe eniyan ni
Aluko. Inu mi dun wi pe mo gbo ikilo awon eniyan," Fayose se alaye re bee.
Ninu oro oluranlowo pataki
Gomina Fayose nipa oro to n lo ati awon iroyin ayelujara, Ogbeni Lere Olayinka,
se alaye Aluko gege bi onisokuso ati alatenuje
eniyan to tori amala dudu ba won gboku rode Oyo.
"Ti Aluko ba wa bayin lati so gbogbo ohun to so, o ye ke e buserin lasan ni. Nitori oun gan-an fun ara re ti so wi pe, idi ti oun fi n so ohun ti oun so ko ju bi gomina ko se yan-an gege bi olowo otun gomina lo. Ti o ba gba ipe wi pe gomina ti yan-an gege bi olowo otun re, kiamosa ni yoo pada ko gbogbo oro re je patapata. Sebi onijekuje eda ni won, ohun ti won je lenu ni won mo,” Ogbeni Olayinka so fun awon oniroyin bee.
Ogbeni Olayinka ro awon
eniyan ki won ye ma teti si awon eniyan bi Ogbeni Aluko eleyii ti iwa omolubi
jina si bi sanmo se jina sile.
Wayio, ile ejo ipinle
Ekiti ti ran komisanna olopaa ipinle naa lati lo gbe Ogbeni Tope Aluko lori
esun ijeri eke. Ninu eto idibo gomina to waye lodun 2014, Ogbeni Tope Aluko ni
asoju egbe PDP, eleyii to fi owo bowe wi pe, eto idibo to waye naa waye lai si
magomago. Bakan naa lo tun lo bura ni ile ejo ti n gbo awuyewuye leyin idibo wi
pe, egbe PDP jawe olubori ninu eto idibo gomina naa lai si makaruru.
Bi o tile je wi pe aarin
Aluko ati Fayose to daru lo mu un pahunda, sugbon ibura eke ni esun ti ile ejo
gbedide lati tako Aluko leyin awon asiri to tu han gbogbo aye eleyii to yato si
ibura to se niwaju adajo.
0 comments:
Post a Comment