Smiley face

Ile ejo ko ri Saraki gba sile lowo awon ota



*Kootu tiribuna ti pada gbe esun Saraki kana
*Esun metala ti won fi kan Saraki si n gbona felifeli
Bukola Saraki
Ile ejo to gaju nile yii ti pase fun ile ejo Code of Conduct Tribunal (CCT) lati tesiwaju ninu itopinpin esun metala (13) ti won fi kan aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki. Eleyii ti awon esun naa dale aisododo nipa akosile iye dukia re nigba to wa nipo gomina ipinle Kwara.


Niwaju ile ejo kotemilorun, eleyii to waye ni ogbonjo osu kewaa odun to koja yii (30/10/2015) ni Saraki koko ti gbe CCT lo. Ni ile ejo yii ni Saraki ti ro ile ejo lati pase fun ile ejo tiribuna CCT ki won jawo kuro ninu awon esun ti won fi kan an. 

Sugbon ibi ti ile ejo naa da ejo naa si ko te Saraki lorun. Nitori ile ejo naa tun fi irawo kun irawo ile ejo tiribuna lati tesiwaju ninu esun metala ti won fi kan Saraki ni.

Ni ile ejo kotemilorun ti Saraki pe yii ni won ti si iwe ofin, eleyii to so iru agbara ti Code of Conduct Tribunal ni lori awon esun ti won gbe siwaju re.

Leyin eyi ni Saraki tun ejo naa pe si ile ejo to gaju patapata (Supreme Court), nibi ti Saraki ti n beere fun ohun kan naa wi pe, ki ile ejo jawe jokoo jee fun CCT. Igbejo yii lo waye ninu osu kejila odun 2015. Nibi ti ijoko ile ejo naa ti sun igbejo naa siwaju di ojo karun-un osu keji odun 2016.

Gege bi oro awon agba, won ni baa ba dogun odun, dandan ni ko pe. Ta a si dogbon osu, ogbon osu ko ni salai ko dandan. Eyi gan-an lo sele lojo Eti to koja yii nigba ti won tun se igbedide ipejo Ogbeni Saraki.


Ninu eto idajo naa, eleyii ti igbimo onidajo bi meje eleyii ti onidajo agba ile Naijiria, Mahmud Mohammed, n se adari fun, ni won tun pada dajo naa wi pe, ko si oro ninu ohun ti Saraki n beere fun. Nibe naa ni won tun ti pase fun CCT lati tesiwaju ninu ise re lai si ifoya kankan.

Nibayii to ti wa fojuhan gbangba wi pe, agbara Saraki ti pin lati si CCT lowo ise lori esun metala ti won fi kan an naa. To si tun je wi pe, gbogbo esun metala ti won gbe siwaju Saraki ni ko ti ri awijare kankan ro to le mu bo lowo CCT. Ohun ti o pada sele leyin ti CCT bagbe ejo re dide ni ko ti yenikan.

Sugbon sa, ninu awon alaye ti Saraki ti se saaju niwaju igbimo onidajo CCT, o ni ohun to gbe oun wonu wahala yii kii se nipase esun aisododo akosile dukia ti CCT gbe lori. Bikose awon kan tinu bi nipa bi oun se jawe olubori gege bi aare ile igbimo asofin agba.
 
“Mo wa nibi lonii nitori emi ni aare ile igbimo asofin agba. To ba je wi pe omo ile igbimo lasan ni mi, mi o ni debi,” oro yii ni Saraki so niwaju kootu CCT nigba ti won fiwe pe lodun to koja.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment