Awon eniyan bi ogoji (40) lapapo
ni won ti fi ife han bayii lati dije fun ipo gomina ipinle Ondo eleyii ti yoo
waye ninu odun yii.
Ninu egbe oselu All
Progressives Congress (APC), ogbon eniyan ni won ti nawo soke bayii lati dije
ninu eto idibo abele egbe oselu naa. Ninu eto idibo yii gan-an ni won yoo ti ma
mo taani yoo soju egbe onigbale lati dije ninu eto idibo fun ipo gomina ti yo
waye ninu osu kewaa odun 2016.
Bakan naa, awon eniyan
mewaa lati inu egbe osele Peoples Democratic Party (PDP) ni won ti n mura sile
fun eto idibo abele egbe alaburada. Eleyii lo mu iye apapo gbogbo awon oludije
naa je ogoji lapapo.
Awon oludije fun egbe PDP
ni Komisanna fun eto idajo nipinle Ondo, Eyitayo Jegede, Komisanna fun eto
ayika, Sola Ebiseni, Hon. Kingsley Kuku, Hon. Bakitta Bello ati Hon. Saka Lawal.
Awon yoku ni Ogbeni Rotimi Jegede, Omooba Nekan Olateru-Olagbegi, Ogbeni
Bamiduro Dada ati Hon. Gbenga Elegbeleye.
Awon oludije labe asia
egbe APC ni Rotimi Akeredolu (SAN), Dr. Segun Abraham, Senato Ajayi Boroffice,
Alhaji Jamiu Ekungba, Arabirin Jumoke Anifowose, Awodeyi Akinseyinwa Apata,
Hon. Sule Akinsuyi, Olakunle Osunyikanmi, Odunayo Akinrinsola, Foluso Adefemi
ati Bukola Adetula.
Awon yoku labe egbe oselu
onigbale ni Dr. Bode Ayorinde, Olubunmi Agbaminoja, Oloye Segun Ojo, Sola Iji,
Hon. Victor Olabimtan, Senato Tayo Alasoadura, Adegbonmire, Light Ariyomo, Paul
Akinterinwa, Ayo Akinyelure, Olusola Oke, Ife Abegunde, Akinyinka Akinnola ati
Dr.Tunji Abayomi.
0 comments:
Post a Comment