Olajumoke Orisaguna |
Opolopo ni i pokiki
Olajumoke Orisaguna omo oniburedi gege bi oloriire ti Edumare da lola ojiji
pelu bo se se alabapada agbaoje ayaworan ati olorin ti n je TY Bello. Laaarin
iseju kan, omo oniburedi di orekelewa oba onise oge. Aimoye awon ile ise alaso
oge ni won ti bere si sanwo tabua fun un latari igbelaruge ati ipolowo ti n se
fun awon oja won. Okan ninu awon banki igbalode tile ti yan gege bi asoju won
eleyii ti aimoye naira si ti sokale si i lapo. Aimoye awon eniyan ni won
gbadura ki won ba iru aanu ati ore ofe bee pade.
Sugbon kini kan se pataki
ti o ye ka fi kogbon, buredi lo so aye Olajumoke di iyanu. Enikan so fun mi ni
awon akoko kan seyin wi pe, ijakule elomii bere nikete to kawe gboye nile iwe
giga. Nitori wi pe sabuke to gba ti bo o loju.
Iwe eri ni i gbe kiri, o si ko
lati mu ise kankan se yato si ise ti sabuke re le fi le e lowo. Aimoye awon
eniyan ni i wase lode toni, ki i se wi pe kosise, iru ise ti won wa ni ko
wopo. Sugbon ni awon akoko kan ninu igbe
aye eda, a ni lati gbe igberaga ti sibi kan, ki aye le dun gbe fun wa. Ohunkohun
ti a ba ri lati fi pawoda, e je ka gbiyanju lati mu sa loogun titi ti igbega wa
yoo fi de. Meloo ninu awon odo asiko yii ni won setan lati lo kose owo leyin ti
won jade ileewe?
E ma je ki ise kankan ti wa loju lati se niwon igba to ba ti
je ise to gunle otito. Eniyan le ma sise asobode lonii, eleyii ko yi kadara re
pada tabi iru eni ti Edua oke so wi pe yoo je laye. Eniyan le se alagbafo debi
ti ogo re wa. Ti a ba n gbadura wi pe ki Oluwa bukun wa, ki i se nipa jijoko
sile lai se ohunkohun. Ti e ko ba nise lowo, mo ro yin ki wa ise kan se.
O le
je ise kekere, sugbon ninu igbinyanju yin ni Edua o ti saanu fun yin. Koda,
eniyan le sise ofe tori ko ma ba joko sile lasan. Ti Jumoke ko ba ta buredi ko
le de ibi to de lonii. Ti eniyan ko ba ri ohun to fe, a ma fe ohun to ba ri
nigba mii. Kadara eda wa lowo Eledumare oba ogo. Oosa oke nikan lo si mo ona
teda o gba soriire laye.
E ma
so ireti yin nu ninu Naijiria. E fi ireti sinu ogo ati ola re. O daju wi pe
leyin okunkun, imole n bo dandan ni. E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment