Smiley face

Ogun awure to daju (2)



#Ogulutu
Ohun gbogbo ni eni lati se lati mu awon onibara yin feran yin tayo oja ti e n ta. Awon onibara yin ni lati nife yin gege bi eniyan, ki won to le ma kowo le oja yin nigba gbogbo. Idi ni yii ti mo fi so wi pe, iwa ati iha ti e ko si awon onibara yin se pataki. 


Eni lati ko bi won se n lo ede aponle, eni lati se opolopo suuru pelu awon onibara yin, isoro awon onibara yin si gbodo jeyin logun ju lo. Bakan naa ni e gbodo fi ye awon onibara yin wi pe, awon l’oba, ninu isesi ati iwa yin si won. Awon nnkan ti mo menu ba lose to koja ni yii.

Lose yii, orisii ogun awure meta to daju ti mo ko lowo baba mi ni mo fe gbe sanle bi Ifa-olokun-asorodayo.

Gege bi oloja tabi onise-owo, eni lati maa ronu ara otun eleyii ti enikeni ko seri ni ilana ise ti e yan laayo. Ara otun naa le ma je ohun to tobi, sugbon ko je ohun tuntun ti yoo mu inu awon onibara yin dun. Awon nnkan bayii ma n wu kositoma lori, eleyii ti o si fe maa mu won sun mo yin nigba gbogbo.

Lori ise ti e n se, ona wo le tun le gba eleyii ti yoo tun fi jo aye loju ju bi won se n se e tele lo?

Eleekeji ni sise amulo ogbon tuntun. Ohunkohun ti awon ti e jo n sise kan naa ba n se, te ri wi pe o n mu itesiwaju de ba won, eyin naa le sare mulo. Ti iru ogbon naa ko ba ye yin, e sun mo awon to ye ki won la ye yin. Ti won ba n te awon kositoma lorun ju bi eyin se n se lo, anfaani wa wi pe, oseese ki awon kositoma fi yin sile lo ba won.

Elekeeta, e ri daju wi pe e n fi gbogbo igba wa imo lori ise yin tabi okoowo yin. Awon nnkan to ba ru yin loju, e ma sinmi titi te e fi ni idaniloju imo alaye nipa won. Ohun ti won pe loga ise leni to n wa imo tuntun loorekoore.

Mo royin lati se amulo awon awure ti mu la kale yii, o damiloju wi pe ise ati okoowo yin yoo tun lo soke si i. Olayemi Olatilewa ni oruko mi, awon ti won ka mi n’iroyin ni mo mo leeyan pataki. Awon eeyan pataki ti won gbayi bi isana eleta.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment