#Ogulutu
Bi e ba je oloja, ti e ko ba ki n se
akosile oja yin, e ko se daadaa to gege bi onisowo gidi. Bi e ba ni ninu ero
lati gberu tabi lati lo siwaju, e gbodo ko bi won se n se akosile oja. Oloja
mii ko le so pato iye oja to wa ninu soobu re, ohun ti ko dara ni.
Akosile oja
wa se pataki, awon nnkan bayii fi wa han gege bi eni to mo nnkan ti n se. A ni
lati se akosile iye oja ti a ra si ori igba ati eyi to wa lori igba tele. Iye
owo to wole si yin lapo ati eleyii to jade. Ohun to tun wa se pataki julo ni
akosile bi e se n ta awon oja naa. Oja meloo le ta lose to koja, meloo le ta
lana, oja meloo lo ku ninu igba yin, se gbogbo re se regi pelu owo to wole si yin
lapo?
Bakan naa ni e ni lati maa se akosile
iye te n je lere ati awon owo ti e n naa jade. Akosile yoo je ke e mo boya e n
jere tabi e n padanu. Akosile yoo je ke mo nipa irinajo yin, se n lo si iwaju
ni abi e n pada seyin. Nnkan bayii yoo si le ran yin lowo lati le se atunse si
ibi ti ipalara ti n wole. Oloja mi wa to je wi pe a won omo ise re ni won jale oja re. Sugbon
nigba ti kosi akosile to giriki nipa oja re, o seese ko ma tete fura ni kiakia.
Maa duro nibi, sugbon awon agba lo wi
pe, ere loloja n je. Gbogbo ise taa ba se, ire nla ni yoo je ti wa. Ase.
0 comments:
Post a Comment