Smiley face

Awada kerikeri: Odaran meta

"**E TUN WA GBO O**

Owo te awon meta kan fun esun ole jija, won si ko won lo sile-ejo. Leyin opolopo atotonu, ile-ejo rii pe awon eeyan ohun jebi esun ti won fi kan won.

Eni akoko ji agolo sandinni kan, adajo si pase ko lo sewon odun meta pere. Eyi ri bee latari pe, eja meta lo wa ninu agolo sandinni ohun.

Kireeti eyin kan ni enikeji ji, adajo si pase ko lo sewon ogbon odun. Nitori ogbon eyin lo wa ninu kireeti kan.


Loju ese nibe ni odaran keta daku ninu ile-ejo, tawon eeyan si bere sii jii.

E ni ki lo sele?
.
.
.
.
.
.
.
.
.
.
.
.
Apo RAISI kan lo ji gbe....".


- Yanju Adegboyega
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment