Awujale, Amosun, Alake |
Sebi awon Yooba lo wi pe,
agba ki i wa loja ki ori omo tuntun o wo. Ibi ti erin meji ba si ti n ja, awon
agba ni koriko ibe ni i fori fa eyi to ju ninu iya. Awon nnkan yii ni Senato
Ibikunle Amosun to je gomina ipinle Ogun ro papo to fi kesi Oba Sikiru Kayode
Adetona, Awujale tile Ijebu ati Oba
Adedotun Aremu Gbadebo, Alake tile Egba si ofiisi re to wa ni Oke-Mosan niluu
Abeokuta lati ba won pari aawo to be sile naa.
Leyin ipade idakonko ti won jijo
se papo, idunnu nla ati erin keeke ni awon oba mejeeji gbe jade lati inu yewu
gomina ti ipade naa gbe ti waye.
Ti e ko ba gbagbe, wahala
yii lo be sile laaarin oba meji yii nigba ti Alake se apejuwe Awujale gege bi
oba ti ipo re kere julo ninu awon omo Odudua atewonro. Ninu alaye re, ni Alake
ti gbe ara re saaju Awujale leyin to daruko Ooni Ile-Ife gege bi oba onipo kinni,
Alaafin Oyo tele, oba eleeketa to nipo ju ninu awon omo Odudua gege bi alaye
Alake ni Oba Benin. Leyin eyi lo daruko ara re to si fi Awujale si isale patapata.
Oro yii ko ba ibi to dun lara Oba Sikiru Adetola ti gbogbo eniyan gba gege bi
asaaju oba gbogbo ile Ijebu pata. Eleyii naa lo si mu Awujale fesi ranse wi pe,
Alake ki i se oba ile Egba, oba Ake lasan ni i se. Eleyii to se alaye Alake
gege bi okan lara awon oba ti irawo re bintin julo nile Yoruba.
Ninu oro gomina Amosun leyin ipade
yii, bi o tile je wi pe inu didun ni gomina fi n soro, sibesibe, gomina Amosun
ko soro ba iyanju aawo kankan laaarin awon oba mejeeji naa. “Mo mo wi pe ara
yin yoo ma re galigali lati mo ki ni ababo ipade wa. Sugbon mo fe fi dayin loju
wi pe ko si ababo kankan nitori ko si ohunkohun to sele. Mo ti gbiyanju lati fi
emi imoore han nigba ayeye ogoji odun ipinle Ogun, ife inu mi lo si je lati
kesi awon oba nla meji yii leekansi lati fi emi imoore han leekansi fun aduroti
won,” Amosun se lalaye bee.
Oba Sikiru Adetona, Awujale tile
Ijebu ko lati ba awon oniroyin soro pelu bo se fi ogbon agba yo won sile nigba
ti Alake tile Egba, Oba Gbadebo ni abewo lori awon osise to dase sile lo gbe
ori ade wa si ofiisi gomina. Bayii ni onikaluku won se, ti won fi ko sinu oko
ti won si lo kuro ni ofiisi gomina.
0 comments:
Post a Comment