Lowolowo bayii, ile eko
ajo naa to kale si ilu Kano ni iroyin so wi pe, awon eniyan tuntun ti won fe
gba sise naa ti n gba idanilekoo saaju ki won to wose. Awon eto ti won se
nibonkele yii ni won lo ni i se pelu awon oloselu kan ti won lenu nibe ni ona
ati pese ise fun awon eniyan ti won.
Gege bi okan lara awon
osise ibudo idanileko yii se so, eni to ko lati daruko ara re, " O je ohun
ijoloji bi won se fi awon oruko won sowo siwa lati Abuja lai se wi pe eto
igbanisise kan tile waye. Ti eto igbanise ba fe waye, ohun ti gbogbo ara ilu
yoo gbo nipa re ni."
“Ati ojo keje osu keta
odun yii ni ati pejo silu Kano nibi fun igbaradi. Okan ninu awon oloselu to wa
nile igbimo asoju-sofin to wa lati ekun idibo adugbo wa lo fi ise naa ta mi
lore. Mo si dupe fun ore ofe ti mo ri gba naa," okan ninu awon ti won on gbaradi
nibudo Eko naa se alaye bayii.
Gege bi alaye Arabirin
Amina Nqua Habiba Aliyu to je alarina fun ibudo idanileko naa, se alaye wi pe,
ko si ohun to jomo bee rara. O tun salaye wi pe, awon ko si nidi eto igbanisise,
idanileko awon ti won gba sise lasan ni ise awon. Bakan naa lo tun fi kun wi
pe, bi o tile je wi pe, atejade kan lati odo ijoba so nipa igbasise awon
egberun marun-un eniyan, o ni sugbon aba yii ko ti wa si imuse.
0 comments:
Post a Comment