Omoge pelu MC Olu Omo |
Awon Yoruba bo, won ni
orisiirisii obe laari lojo iku erin. Eyi gan-an lo waye lojo ti okan lara awon
oloye egbe awako NURTW, Ogbeni Musiliu Akinsanya ti gbogbo eniyan mo si MC Olu
Omo Osodi, se ojo ibi. Ariya ti won fun
ni akole "Braless Night" yii ni won ti ro awon omoge ti n bo nibe
lati ma wo komu labe aso.
Eleyii to mu pupo awon oyan omoge oju agbo naa ma
gbon jolojolo nigba ti ori oyan awon kan ta sita sonso. Ayeye ojo ibi yii lo
waye nile ijo The Palace to wa ni agbegbe Ikeja nipinle Eko lojo Aje to koja
yii. Yato si awon omoge ori irin ti won
kunbe fofo, awon osere onitiata naa ko gbeyin. Die lara awon osere tiata to wa
nibe ni Mide Funmi Martins, Bimbo Thomas ati Sunkanmi Omobolanle.
Apero lori YORUBA DUN
0 comments:
Post a Comment