*Iwe eri agunbaniro NYSC ni won yoo fi ma ya owo naa
Aare Muhammadu Buhari ti
se ifilole bilionu mewaa owo naira gege bi owoya fun awon odo lati da okoowo
alabode sile. Eto ti won pe ni N10 billion Youths Entrepreneurship Support
(YES) ni yoo mu adikun ba isoro airikansekan ti n ba awon odo ile yii finra.
Minisita ti n rise ileese, karakata ati idokoowo, Ogbeni Okechukwu Enelamah, se
alaye wi pe, eleyii wa ninu ileri ijoba to wa lodo yii lati pese ise fun
ogunlogo awon omo akekoo jade ti won woju Oluwa fun iyanu ise sise.
Ninu oro minisita niluu
Abuja lo ti n ro awon eniyan ti wo yo ma je anfaani owoya naa lati ri daju wi
pe, awon da awon owo naa pada. O ni dida awon owo naa pada yoo mu awon eniyan
mii je anfaani kan naa to mu won kuro leni ti ko nise lowo.
Gege bi oro ogbeni Waheed
Olagunju, eni to je alakoso fun Bank of Industry ti won yoo ma se kokakari eto
eyawo naa so wi pe, ohun pataki ti awon odo yoo ma fi se oniduro lati ya owo ni
iwe eri agunbaniro NYSC won.
Afolabi Imokhuede to je
amugbalegbe pataki fun igbakeji aare ko sai soro nibi ifilole naa to waye niluu
Abuja. Ogbeni, Imokhuede so wi pe, ipese
ise lopo yanturu wa lara ohun to je ijoba to wa lode yii logun pupo ju. Bakan
naa lo si so yananya-yananya wi pe, ise to n lo bi milionu meta abo nijoba yoo
pese laaarin odun meta.
0 comments:
Post a Comment