Oku Ome Enyi |
Awon
Yooba bo, won ni owo tada mo ni kada lehin. Iku ogun ni i pa akikanju, omi
ni pada wa pa omuwe lodo. Okan ninu awon
omo asewo ilu Abuja ti oruko re n je Omidan Ome Enyi lo ti se agbako iku ojiji
bayii lenu ise nabi to yan laayo. Omobirin eni odun marunlelogbon (35) ni won
ba oku re ninu ile itura kan to wa ni agbegbe Kubwa to wa niluu Abuja. Ome to
je omo ilu Calabar lagbo wi pe oun ati okan ninu awon onibara re kan jo wole
sun lale ojo Aje to koja yii fun “igbadun alailopin”.
Sugbon
nigba ti ile yoo fi mo, oku Ome nikan ni won ba nile gelete. Okan ninu awon
agbale ile itura naa lo sakiyesi oku omobirin naa ki won to gbe lo si ile
igbokusi. Titi di akoko akojopo iroyin yii, enikeni ko ti le so pato iru iku to
pa omidan orekelewa ti n fidi re pawo naa. Bakan naa ni ko si eni mo ibi ti
onibara re fara pa mo si.
0 comments:
Post a Comment