Egbe awon osise ti elepo
robi ati afefe gaasi nile yii ti a mo si NUPENG, (Nigeria Union of Petroleum and Natural Gas Workers)
ti so wi pe, oseese ki owongogo epo robi o tesiwaju ayafi ti ijoba ba gbe awon
igbese to ye lasiko.
Eleyii lo jeyo pelu bi
awon alagbata epo robi ati awon ileese aladani ti won sowo epo robi se fesun
kan ile ise iwapo ile Naijiria ti a mo si NNPC (Nigeria National Petroleum Corporation)
nipa ilana emi-nikan-ni-i-da-nnkan-mi-se ti won gunle. Won enikan ki i je
awade; bakan naa nigi kan ki i dagbose. Sebi bu fun mi n bu fun o lopolo n ke
lodo.
Aare NUPENG, Ogbeni Igwe Achese, se lalaye wi pe, ohun ti o
le mu nnkan pada bosipo ni ti ajo NNPC ba setan lati fowosowopo pelu awon eka
ti oro naa kan lawujo. Sebi awon agba naa ni won wi pe, ajeje owo kan ko gberu dori.
"Ijoba apapo ni lati
gbe igbese to ye nipa agbekale ti yoo mu nnkan pada bosipo. Eleyii ti pupo re
ni i se pelu awon eto to romo bi won se n gbe epo nibudo iwapo ati bi won se n pin-in
kaakiri tibutoro ile yii. Sebi ti a ko ba fe ki n kan o baje, o ni baa ti n
se," Ogbeni Achese
se alaye naa bee.
0 comments:
Post a Comment