Leyin rogbodiyan to be
sile ni agbegbe Mile 12 to wa niluu Eko l’Ojobo ose to koja yii (03/03/16),
okunrin kan ti oruko re n je Daniel Igba lo ti ke gbajari sita wi pe, awon kan
ja omo gba lowo oun nigba ti wahala naa gbena kari.
Ninu itaporogan to waye
laaarin eya awon Hausa inu oja Mile 12 ati awon Yoruba ni Ogbeni Igba ti gbe
padanu omo re, eni odun kan ati osu meje ti ko si le so pato ibi ti omo na wa
bayii.
"Ile ni mo wa ni
nnkan bi ago mewaa aaro nigba ti wahala naa wo inu adugbo wa. Mo sare gbe omo
mi lati sawo ile lo. Sugbon bi mo se n salo ni awon eniyan naa sare tele mi
leyin, won lemi ba, won si bere si ni na mi. Won fi ake sami lori ati lowo. Ni
akoko yii, mo si gbe omo mi mora sibe naa. Bi mo se ni ki n tun dide ki n maa
salo ni mo subu. Bayii ni won se ri omo naa jagba lowo mi. Lati igba naa, a ko
ti ri omo wa. Iya re ko si nile ni akoko naa, o lo si ileewe," Ogbeni Igba
se alaye naa bee.
Ninu ija nla to waye yii
ni aimoye emi ati dukia ti gbe sofo ko to di wi pe awon omo ologun ile wa to wa
dawo rogbodiyan naa duro.
0 comments:
Post a Comment