Mike Adenuga |
Ni owuro yii, mo fi akoko
mi sile lati ka nipa aseyori Mike Adenuga, alase ati oludari ile ise ibanisoro
Gbobacom. Ohun to ta mi kan ko ju iroyin tuntun nipa re eleyii to n se afihan
re gege bi enikeji to lowo ju lo bayii ni ile Afirika gege bi atejade tuntun Magasiinni
Forbes agbaye odun 2016. Ninu awon eniyan bi merinlelogun (24) ti Forbe se
alaye won gege bi borokini olowo julo ni ile adulawo, ipo kinni si ni Dangote
dimu, Adenuga se ipo keji. Femi Otedola wa nipo kerinla nigba ti Arabirin
Folorunso Alakija wa ni ipo kerindinlogun.
Iwadii Forbes fihan wi pe,
ohun ti Adenuga n je lere ti fo fere lati bilionu merin owo dollar ile Amerika
lodun 2015 bo si billion mewaa owo dollar ninu odun 2016.
Ohun kan ti mo fe fi dayin
loju ni wi pe, ki i se gbogbo eniyan to rise gidi se ni won sanwo riba fun
enikan ki won to fun won nise se. Bakan naa ni ki i se gbogbo olowo ile
Naijiria ni won jale tabi gba ona alumonkoroyi ki won to deni atata lawujo.
Eyin naa le ti apata dide,
ke e si di bee di eniyan atata lawujo.
Aseyori eda bere lati ibi
ero okan re. Ohun ti e dimu gege bi otito ni o pada royin lara bi aso. Ti e ba
gbagbo wi pe e pada doke, mo fi n dayin loju wi pe, ohun to seese ni. Nitori ero
okan yin, igbagbo yin, bope-boya yoo pada royin lara bi aso. Ewu wa ninu
igbagbo yin wi pe, eniyan ko le debi giga laise se wi pe o gba ona alumonkoroyi.
Ti e ba ni iru ero bayii
lokan, ohun ti e n so fun ara yin ni wi pe, e ko peye to lati se asela laye.
Iru ero wo le dimu nipa igbe aye yin? Kini igbagbo yin nipa ojo ola yin? Oni le
koro bi ewuro, sugbon e fi igbagbo yin sinu ola. E ma so ireti aseyori yin nu.
E si ma fi gbogbo igba ro ire nipa igbe aye yin. E ma gbagbe ohun ti mo so
saaju, orisii ero yowu ki e ni lokan, bope-boya, ero okan yin yoo pada royin
lara bi aso. Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ilu Naija olokiki ti n san fun wara
ati oyin lemi n ja fun lojo gbogbo. E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment