*Oba
Akiolu fara mo aba Ambode lati gbe oja Mile 12 kuro
Leyin rogbodiyan to be sile ni agbegbe Mile 12 to kale siluu Eko laaarin awon Hausa oloja ati Yoruba lojo keta osu keta odun yii (03/03/16), OLAYEMI ONIROYIN se abewo si ile iwosan LUTH tiluu Eko lati kan si awon to lugbadi ijamba nibi isele naa eleyii ti won gba itoju lowo bayii.
Nile iwosan yii ni a ti se
alabapade Bolaji Kalejaye, eni odun merindinlogun (16), to kan ijamba lojo
buruku yii nigba ti n bo lati ibudo idanwo Jambu. Sugbon ti ota ibon ba lateyin
eleyii ti ota naa si fo jade nikun re foki pelu awon ifun inu re to ro daale.
Gege bi ohun ti a gbo,
awon eniyan sare gbe Kalejaye lo si ago olopaa to wa nitosi boya iranlowo
kiakia le ti odo won jade sugbon ti awon olopaa naa ko ri ohunkohun se. Leyin
eyi ni Kalejaye tun pada soju popona nibi o ti gbe dawo lule logido.
Ni akoko yii, kosi eni le seranlowo
mo nitori wi pe onikaluku n sare asala fun emi re ni.
Sugbon awon kan ti won mo
omo naa ti won ri nibi o ti gbe n japoro iku ni won sare lo kesi awon obi omo
naa ko to di wi pe won gbe lo si ile iwosan LUTH. Kalejaye ti n gba itoju to ye
lowo awon dokita, sugbon ilera re ko ti pada bo sipo gege bo ti ye.
Nibayii, ijoba ipinle Eko
ti pinnu lati gbe oja to wa ni Mile 12 lo si agbegbe mii. Lori ero yii kan naa
si Oba Rilwan Akiolu ti faramo aba ijoba ipinle Eko nipa gbigbe oja naa kuro lo
si agbegbe mii.
0 comments:
Post a Comment