Smiley face

Ipindokoowo

Ipindokoowo
Mo ti se ileri lati se idanilekoo nipa okoowo sise. Bakan naa, orisiirisii okoowo lo wa ti eniyan le kowo le fun ere to le mu ni di olola. 

Okoowo sise tabi Idokoowo ni orisii okoowo ti a dawo le lori, eleyii ti n pa owo wole fun wa, yala nigba ta n sun tabi nigba ta n se faaji ara wa. 

Lopo igba, iru awon okoowo bayii, ki i se dandan ni wi pe, a gbodo wa loju ise fun arawa ki owo to le wole fun wa. 

Lara iru awon okoowo bayii ni rira ipindokoowo.
Sugbon ki n to tesiwaju, yoo wu mi lati se alaye awon itunmo awon ede to ni i se pelu ipindokoowo. To fi je wi pe, ti mo ba bere awon alaye nipa bi e se le je anfaani ipindokoowo, awon ede ti mo ba n lo ko ni je ajoji si yin.


Share: Eleyii je ipin idokoowo ti ileese okoowo kan ta sita fun awon eniyan lati je alabapin ati alajoni ileese naa. 

Awon ileese olokoowo a ma ta ipin idokoowo won lati ri alekun owo gba wole fun ileese, ni ona lati ri owo sowo siwaju sii ju ateyin wa lo.

Stock: Alaye eleyii ko yato si alaye ti a se nipa share, ede kan naa ni awon mejeeji.

Stock Exchange: Eleyii ni oju oja ti awon ileese nla ti n ta awon ipindokoowo won.
A tun le so wi pe, oja ti rira ati tita ipindokoowo ti n waye. Orisii oja yii to je tile Naijiria ni won pe ni Nigeria Stock Exchange. 

Stockbroker: Eleyii je awon akosemose ti won mujuleja ipindokoowo, ti won bani ra tabi ta ipin idokoowo eni. Awon tun ni a le pe ni alarina laaarin eni to fera tabi ta ipindokoowo ati gbagede oja ti won ti n ta ipindokoowo awon ileese nla ti a mo si Stock Exchange.
Eniyan kan lasan ti ki i se akosemose ko le lo soja ipindokoowo lati lo ra ipindokoowo fun ara re.

Shareholder: Eleyii ni awon eniyan ti won ra ipindokoowo ileese kan. Awon wonyii ni alajoni ati alabapin ileese naa. Eni to bara share ni won pe ni shareholder.

Shareholding: Eleyii ni apapo iye dukia to je teni nipa ipindokoowo ileese taa ra. Se mo wi pe, bi owo eku ba se mo ni i se fi hori. Apapo dukia enikan ni ileese kan le je milionu kan nigba ti elomii je egberun meji. 

Eleyii ni i se pelu iye owo ti won fi dokoowo naa ni yoo so bi dukia ipindokoowo won yoo se to nipa ere ti won je.

Share Certificate: Eleyii je iwe eri eleyii to n jeri wi pe, eni ti oruko re wa lori iwe eri naa je alajoni ati alajopin ile ise to gbe iwe eri naa jade. 

Iwe eri naa tun se afihan iye ipin to je ti oludokoowo ninu ileese naa. Iwe eri yii ni eniyan yoo gba nikete to bara ipindokoowo ileese kan.

Security: Orisii security ti a n soro ba nibi ki i se eleyii to ni i se pelu alaabo. Itunmo ti ede naa ni yato ti a ba n so nipa ipindokoowo. 

Security ni akosile iwe to le mowo wole fun ni, eleyii ti won le ta tabi ra loju oja Stock Exchange. Apeere eleyii ni Share Certificate.
Koda, eniyan le fi iru akosile iwe bayii yawo ni banki.

Public Offer: Eleyii je anfaani ti ile ise fi sile fun awon eniyan awujo lati wa ra ipin idokoowo ile ise won, eleyii ti yoo mu won je alajoni ati alajopin ileese naa. Iru anfaani bayii fi anfaani sile fun awon eniyan lati ra ipindokoowo taara lai si iranlowo Stockbroker.

Public Liability Company: Ileese to dangajia lati ta ipin ileese re fun awon eniyan awujo gege bi ipindokoowo. Eyi tunmo si wi pe, ileese ti ki ba ki n se Public Liability Company ko le ta ipin re sita fun awon eniyan awujo.

Bond: Eleyii je akosile iwe kan ti n se alaye wi pe,ileese, ajo, tabi ijoba yawo owo lowo awon eni ba won dokoowo papo. Iru awon owo bayii maa ni ele lori, eleyii ti o jasi ere fun awon ti won ko irufe owo bee sile fun awon akoko kan gege bi ajoso igun mejeeji. 

Ma duro nibi lati tesiwaju lose to n bo. Bi o tile je wi pe, mi o ki n se agbaoje ninu eto isuna owo, sugbon ise oniroyin wu mi pupo nitori o fun mi lanfaani lati se awari orisiirisii imo to se koko lawujo.
Bi o tile je wi pe mi o feran okele jije, sugbon bi amala dudu pelu abula ati eran ogunfe ko la n wi. Bi o tile je wi pe mi o gbadun ohun ti n sele lowolowo lorileede mi Naijiria. Sugbon igbagbo mi ko ye nipa ojo ayo, ogo ati ola ti ko ni pe de. Ki Oluwa bukun Naijiria, ilu mi.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment