Aluko ati Fayose |
Oro yii ni Gomina Ayodele Fayose so fun awon oniroyin leyin ipade bonkele to waye pelu Ogbeni Tope Aluko, akowe egbe PDP ipinle Ekiti tele. Ipade iyanju ikunsinu laaarin awon mejeeji yii lo waye niluu Eko lojo keta osu kerin odun yii.
Ogbeni Aluko lo fojuhan lori telifisan kan niluu Eko ninu osu keji odun yii nibi to ti n tu asiri bi oun ati Ogbeni Ayo Foyose se gba ona eru lati bori idibo gomina to waye ninu odun 2014 nipinle Ekiti.
Bakan naa lo tun menuba bi aare ana, Goodluck Jonathan se gbe aimoye owo dollar ile Amerika kale ati awon soja lati ri wi pe, Ayodele Foyose lo wole ni gbogbo ona.
Ogbeni Aluko ko sai fikun alaye re nipa idi pataki to fi tu asiri naa faye, eleyii to wi pe, Fayose dale oun leyin to wole gege bi gomina.
Leyin ipade bonkele to waye lojo keta osu yii (03-04-16), Ogbeni Aluko duro legbe Fayose niwaju awon oniroyin to si jeri si wi pe, alaafia ati isokan ti pada si aarin awon.
Sugbon oro tun ba ibo mii yoo lojo keji ipade naa, nigba ti Aluko tun figbe ta wi pe, alaafia ati isokan ko ti joba laaarin ohun ati Foyose.
Ogbeni Aluko ni etan ni won fi gbe ohun de ibi ipade ojo naa.
"Awon oloye egbe ni won pe mi fun ipade lati jiroro ni ona lati mu egbe PDP tesiwaju. Lojiji ni mo ri Foyose to wole. Leyin eyi ni iyawo mi to ba mi wa wole sinu ibi ti ipade ti n lo lowo, to si wi fun mi pe, awon oniroyin ti wa nita.
Okan iyawo mi ko bale bo se n soro fun mi. Leyin eyi, mi o mo ibi ti iyawo mi wole si mo. Fun abo ebi mi lo je ki n se ife Fayose pelu awon ohun ti mo so.
Mo si wa lori awon oro ti mo so nipa Fayose losu keji odun. Eniibi, odale, olote, onimakaruru ni Fayose. Mo toro aforijin lowo omo Naijiria, asise nla gbaa lo je fun mi wi pe mo lo sibi ipade naa," Ogbeni Aluko tun alaye re se bee.
0 comments:
Post a Comment