*Ikunsinu laaarin
Osoba ati Amosun si wa sibe bi oke olumo
*“Talo so wi pe ija wa laaarin emi ati Amosun?” - Tinubu
*Akitiyan gomina
2019 ti n lo labenu nipinle Ogun
Osoba ati Tinubu |
Lara awon to peju sibi ipade naa ni Oloye
Bola Tinubu, Oloye Bisi Akande, Ogbeni Rauf Aregbesola ati Gomina Abiola
Ajimobi. Awon yoku ti won wa nibi ipade naa ni igbakeji Gomina ipinle Eko,
Arabirin Oluranti Adebule, eni ti n soju Gomina Ambode, Gomina ipinle Ekiti
nigba kan ri, Otunba Niyi Adebayo, Oloye Pius Akinyelure, Senato Gbenga Obadara
ati Omooba Segun Adesegun.
Sugbon sa, Gomina Ibikunle Amosun
lati ipinle Ogun ko fojuhan nibi ipade naa. Enikeni ko ri igbakeji re, Arabirin
Yetunde Onanuga. Bakan naa awon oloye egbe APC lati ipinle Ogun ko si nibi eto
naa rara.
Leyin ipade to waye naa, Gomina
ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola baba Kabiru ba awon oniroyin soro nipa ibi
ti ipade ti won se fun odinindi wakati meta naa yori si.
“Inu mi dun lati kede re fun yin wi
pe, Akinrogun Aremo ti pada sinu egbe itesiwaju. Gbogbo ede-aiyede to suyo pata
lo si ti di afiseyin teegun un fiso,” Ogbeni Aregbe se alaye re bee.
Bakan naa ni Oloye Bola Tinubu ko sai
fi idunnu re han nigba ti n ba awon oniroyin soro nipa bi Olusegun Osoba se
pada wale. Eleyii to se apejuwe re gege bi igbese rere fun egbe itesiwaju. Nibe
naa ni awon oniroyin ti n beere nipa aifarahan gomina Ibikunle Amosun, ko ma lo
je wi pe inu gomina ko dun si igbese to waye naa. Ohun ti oko Oluremi so ni yii:
“Kosi enikeni ti a yo sile seyin
rara. Okan soso ni gbogbo wa, ati gomina ipinle Ogun. Abi enikan so fun yin wi
pe a n ja bi? Ninu ero yin lasan niyen wa. Okan soso nigbogbo wa. Igbiyanju ti
wa si ni lati mu Naijiria tesiwaju. Bakan naa si ni akitiyan wa da lori ki ile
Naijiria le jajabo lowo imunisin odun merindinlogun ti PDP ti fi bale je,”
Tinubu se alaye naa bee.
Fun awon to ba kiyesi bi oselu ipinle
Ogun se n lo, leyin akoko die ti Senato Ibikun Amosun wole ni aarin oun ati Osoba
ko ti gun mo. Lara esun ti Osoba si fi kan Amosun ko ju wi pe, awon mudunmudun
to ye ko maa bo si owo awon omo egbe APC ti won jise-jiya fegbe ni Amosun fi n
dun won. Eleyii to je wi pe, awon to tele Amosun wa lati inu egbe ANPP ni won
jo n se apapin. Rugudu naa de gongo to fi di wi pe, Oloye Osoba fi egbe APC
sile pelu awon emewa re bo sinu egbe SDP.
Bakan naa, Senato Adeola Olamilekan
ti gbogbo eniyan mo si Yayi ti n soju ekun Iwo-oorun Eko nile igbimo asofin
agba l’Abuja fe gbiyanju lati rekoja lo si ipinle Ogun to je ipinle re lati dije
fun senato. Sugbon ohun ti a gbo ni wi pe, Amosun ro Tinubu lati parowa fun
Yayi lati jawo ni ona lati le fi anfaani sile fun eni ti Amosun fe ko dije. Tinubu
gbo si Amosun lenu, eleyii lo fi mu Yayi lo pada tun apoti idibo senato re gbe
nipinle Eko. Gege bi oro awon agba, won ni ti awo ba ki fun ni, a a ki fawo
pada ni. Bu-fun-mi-n-bu-fun-o si ni opolo n ke lodo.
Senato Yayi yii lo tun
pete lati dije fun ipo gomina Ogun lodun 2019 pelu atileyin Tinubu bayii. Aba
yii tun ni Amosun tun un gbiyanju lati tako latari eni tie kan to ni nipamo to
fe gbe ipo gomina fun lodun 2019. Awon nnkan wonyii si ti bere si fa ikunsinu
laaarin Tinubu ati Amosun eleyii ti ko ti han sita gedegbe.
Gege bi alaye awon onwoye lagbo
oselu, won ni oseese ki Tinubu fe lo Osoba lati yi Amosun lagbo dasina ninu eto
idibo gomina ipinle Ogun lodun 2019. Sebi
awon kan lo wi pe, ota ota mi, ore mi ni i se. O seese ko je idi ti Tinubu fi
fa Osoba mora ni yii. Eleyii to si mu Amosun takete bi abata ti n se bi eni wi
pe ko bodo tan.
0 comments:
Post a Comment