Smiley face

Eleyii to kere ju, lo buru ju lo


Eleyii to kere ju, lo buru ju lo

Eran nla, eran agbija, leran ti won pe ni kunnugba. Awon agba ode gba wi pe, eniyan bi meje (7) leran yii n pa lodun kan. Kinihun ololaaju ni i pa to ogorun marun-un (500) eniyan laaarin odun kan soso. Agbamurere a ma pa to ogorun mejo (800). Nigba ti akeeke a ma pa to egberun meje (7,000) eniyan laaarin odun kan kaakiri gbogbo agbaye. Ejo afayafa ni awon onwoye so wi pe, a maa pa to egberun mewaa (10, 000) eniyan lodoodun.


E wa gbo, eyi to joniloju ju nibe ni yii. Awon onimo isegun ni efon, ti ko ju bintin lo, n pa awon eniyan ti won le ni milionu meji abo (2.5m) lodun. Beeni, eleyii to kere ju, lo buru ju lo.

Iwa irira to kere ju, eleyii ti awon eniyan ki i se akiyesi re kiakia yara seku pani. Iru awon iwa irira (ese) yii si le ba ajosepo wa pelu Olorun je. Ka maa soro oloro leyin, iro keekeke pipa ti ko joniloju lewu lopolopo. E je ki a se akiyesi awon iwa irira keekeke ti a n wu lojumo, awon nnkan bayii lagbara lati gbe wa subu. Bakan naa, e ma se je ki ohunkohun di yin lowo lati gba adura si Olorun tabi lati fi akoko perete sile fun Olorun aseda yin lojo kan. Pipadanu iru awon akoko bayii je ohun to lewu.

Nje eyin mo wi pe, ti won ba po iyo mo suga, ti eera ba debe, sugba nikan yoo gbe ti yoo si fi iyo sile. Kini eleyii ko wa? A ni lati le se idamo awon ore gidi lati barin. Orisii ore ta a ni nipa ninu irin-ajo wa laye.

Bi e ba n gbiyanju ohun kan ti ko ba bo si, e wa ogbon mii da, e wa oko ibomii lo, sugbon e ma paro Aseda yin. Sebi gbogbo wa loye wi pe, igi a ma paaro ewe sugbon igi kan kii paaro gbongbon idi re.

Awon agba ni eni a baa naja laa wo, enikan ki i wo ariwo oja. Orisiirisii onibaje eda le ma ba pada ninu igbiyanju yin laye. Nitori  inunibini ko kan tai mo iwa wu. E kotiikun sohun ti awon asebaje n so nipa yin.

E ri daju wi pe e ko  gbe igbe aye familete-n-tuto pelu enikeni. E koju mo igbe aye yin. E si yago fun imele lenu ise ti e n se. Ki n to ma lo, e ma gbagbe, eniyan to ba ba elede woya-ija ninu erofo ni ko lori pipe. Nitori inu elede yoo pada dun, ara eni ba eleda ja yoo si kun fun egbin ati idoti. Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ti mo ba so ireti nu nipa Naija taa ni yoo ba mi fi ireti si? Ki ibukun Oluwa ma ba orileede mi Naijiria. Amin.s
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment