Smiley face

Aye Akamara: Ogbontarigi agbaboolu Naijiria tidi afoju onibaara



Femi Opabunmi
Ile aye ogun. Irin ajo ẹda nbẹ lọwọ Oluwa Oba. Oun kan naa lo si nipinnu rere fun gbogbo ọmọ eda Adamo laye. Sugbon nigba ta a de ile aye tan, ni awon ika eniyan n pa kadara eda da saburu. Sebi won ni ẹkọ ò kọla, aye lo kọla sẹko lara. Irawo to ye ko ma tan kari aye si se bẹẹ wọọkun. Fun awọn to ba ka iwe Iroyin Alariya Oodua ọse yii, ibe ni won yoo ti ka nipa odomode agbaboolu, ti ogo rẹ sẹsẹ fẹ ẹ maa bu jade, sugbon to ti di afoju onibaara bayii, Femi Opabunmi.



Femi Opabunmi wa lara awon agbaboolu Golden Eaglet (Under 17)lodun 2001, ipa ribiribi to ko lo si mu egbe agbaboolu naa se aseyori. Aseyori yii lo tun mu wo inu egbe agbaboolu Super Eagle (Under 23) eleyii to fi je agbagboolu to kere julo ti yoo kopa ninu ife agbaye FIFA todun 2002. Ninu idije towaye lodun 2001, Femi lo gba ami-eye agbaboolu to pegede julo fun ipoketa (Bronze Ball)  ati agbaboolu to gba boolu sawon julo fun ipo keji (Silver Boot). 


Irawo Femi n tan, aimoye awon egbe agbaboolu lagbaye bi Man U, Lyon ati bee bebe lo ni won si n fi ife han si. Omokunrin to ti fi igba kan gba boolu fun Shooting Stars til Ibadan gba Switzerland lọ, igba to ya lo tun un lọ n pawo ni ilu France nibi won ti n ko owo tabua sii lapo. 

Sugbon lọjọ kan, nibi Femi ti n se igbaradi lori papa, ni ategun abaadi kan ti gbe fe si i loju. Ere ni won sebi, bi Femi ko se riran mọ ni yii. Aimoye ise abẹ ni won se fun un niluu France nibi ti awon agba dokita oyinbo alasọ funfun ti gbe pejo lee lori.  Igba to ya ni won gbe wa sile, sebi ti ode ba ti le, ile naa laa fabọ si. 


 Gbogbo ere ni omokunrin yii sa, sugbon ẹpa o gboro. Gbogbo owo to ko pamo lo ti na tan. Gbogbo dukia to ra lo ti lu ni gbanjo. Sibesibe, oju Femi ko la. 

Omokunrin naa ko rowo jeun mọ bayii. Awon Yoruba bo, won ni igba iponju laa mọre. Gbogbo awon ore ati ebi ni won ti sa fun Femi bayii. A tile gbo wi pe Peter Osaze Odemwingie gbiyanju fun un ni awon asiko kan seyin, sugbon nigba to ya lo fa seyin. Gege bi iroyin to jade se salaye re, won ni bọbọ naa ko rowo ile iwe ọmọ re san, ati wi pe, baara lo n tọrọ bayii ni agbegbe Ring Road to wa niluu Ibadan.

Odaju laye, awon ika eniyan sipo lo bi yanrin eti omi. A fi ki oba oke gba wa lowo ẹni binu eni taa mọ.  Amin.

------------------------------------------------------------

Nibi ti mo de yii ni maa ti maa se afihan Alfa Salami ti awon kan tun pe ni Sheu Aseyori. Igba akoko ni yii ti n ma gbe Alfa Salami wa sori ate yii. Ti Alfa Salami ba je oniro ẹda, lati bi nnkan bi odun meji seyin ti mo ti n se afihan won, o ye ki iro ohun ti ja. Sugbon oriyin ati aponle Alfa Salami tun un lo soke si i ni.

Sheu Aseyori
Awon eniyan ti won si kan si won tun pada pemi lati dupe oore nla ti won ba pade. Alfa Salami kii se onise dudu, inu mimo ni won fi n sise ti Oba Alah ran waye wa se. Gbigba adura, owo Olorun lowo, sugbon oba oke yii kan naa ni i fun Alfa Salami se. Kosi iru idaamu tabi ogun teda le ni laye, agbara adura le kapa re. E kan si Alfa Salami lonii, o daju wi pe e ko ni kabamo.  Bakan naa, orisiirisii aisan ti n be eda ja laye to fi mo awon aisan bi Stoke ni Olorun oba fi asiri re sowo Alfa Salami.

E pe won sori ago,  07065865035, ki eyin naa ki won ku ise takuntakun.  

E tun le kan si won ni :

No 13 Seleokela Ado Ekiti,Ekiti State, Ado-Ekiti, Nigeria.

E tun le ka nipa Sheu Aseyori NIBI, NIBI ati  NIBI

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment