Smiley face

Iyato to wa laarin ìdánwò ati àdánwò

ÌDÁNWÒ ati ÀDÁNWÒ
 
Bí ènìyàn bá wo òrò méjèèjì lérèfèé, yóò so wí pé Ì àti À tí ó bèrè àwon òrò náà ni ìyàto won, béè sì rèé gbòn-òn -nà-gbon-on-na bí ojó orí Agbóbímo sí omo rè ni ìyàtò tí ó wà láàrin òrò méjèèjì.

Ìdánwò ni ònà tí à n gbà se ìgbéléwòn fún ni lórí ohun tí Olùdánniwò mò pé eni tí ó n dánwò ní òye rè. Àkókò ìgbáradì àti ìmúrasílè sì máa n wà fún Olùdánwò láti gbáradi sààjú àkókò ìdánwò.

Àdánwò ni àyèwo pàjáwìrì nínú èyí tí Olùdánwò kìí ti í lóye ohun tí yóò kojú béèni kì í sí ààyè fún ìgbáradi tàbí ìmúrasílè.

Pèlú oríkì sókí tí a fún àwon òrò méjèèjì wònyí, e ó ri wí pé ó rorùn láti yege ìdánwò àmó àdánwò a máa fa ológbón jàntolo sí àwùjo Òmùgò nítorí àìlóye àwon ìdojúko tí àdánwò máa n fà fún ni.

Bí ìdánwò ti wà ní ìpele náà ni àdánwò náà ní ìpele, àdánwò le jé lórí isé,aya, oko, omo, èkó, ìbùgbé, alábàásisépò abbl. Kókó nípa rè ni wí pé onàkonà ni àdánwò lè gbà yojú tí yóò wá dàbí eni wí pé òru gànjó ni ènìyàn wà lósàn-án gangan.

Okàn akin àti ìgbàgbó nínú Olórun nìkan ni ènìyàn fi le borí àdánwò. Gégé bí ó ti rorùn fún Olùdánwò láti yege ìdánwò náà ni ó rorùn fún eni tí ó bá ni ìgbàgbó àti ìforítì láti borí àdánwò.

Bí òré àti Ojúlùmò bá torí àdánwò re àkókò yìí sá o tì, fi wón sìlè rántí pé Olùdánwò nìkan ní n dá ìdánwò se tí ó fi n yege. Ìwo ni kí o dinu sí èko ìbànújé tí ayé le fé pò fún ni lákòókò àdánwò, kí o baà le ní okun láti so àpáta àdánwò di òkúta àtègùn.

Kò sí eni tí ó le mú inú re dùn bíkòse ìwo fúnra re. E má gbà fún àdánwò láti rè yín sílè, e sa ipá láti borí rè gégé bí Olùdánwò ti n sa ipá láti yege ìdánwò. 
 
Àdánwò kò ní borí wa oooooo.

A ò sì ní rí àdántán láse Èdùmàrè.

 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment