Pastor Deola Philips |
Agba iyanu eleyii ti n se
gbogbo eniyan ni kayeefi waye lọjọ ketadinlogun osu odun yii, 27-05-16, ni gbagede
Tafawa Balewa Square to wa ni Ilu Eko ọba Akiolu. Ọjọ yii ni ipade Total
Experience ti ijọ Christ Embassy waye. Nibi ti oniruuru eniyan ti gbe gba
imularada, itusilẹ, ati igbala ọkan.
Oniwaasu ọjọ naa ni Pasito
Deola Philips, obirin bi okunrin, ti Jesu onisẹ iyanu n ti ọwọ rẹ se ọpọlọpọ
ohun nla.
Omilegbẹ ero ni Total Experiece 2016 |
Lati irọlẹ bi nnkan bi ago
merin ni ọpọlọpọ awọn eniyan ti n ya wọ gbagede naa pẹlu ireti lati gba ibukun lọwọ
Ọlọrun. Nigba ti ago meje yoo fi lu, omilẹgbẹ ero ti wa nikalẹ lati gbọ ọrọ Ọlọrun.
Ipade naa bẹrẹ pẹlu orisiirisii
orin iyin ati awọn ẹri ọlọkanọjọkan lẹnu awọn ti wọn wa sibi ipade naa to waye
lọdun 2015.
Lara ọkan ninu awon ẹri
naa ni okunrin kan ti aisan ti n da dubulẹ lati ọdun 2013. Gbogbo ẹbi ati
ojulumọ rẹ ni won ti na gbogbo owo tan ni kẹlẹ sugbon ti aisan rẹ ko gbọ.
Ọrọ ọkunrin naa ni a le fi
we ti obirin onisun ẹjẹ inu bibeli. Sugbon lọdun 2015 nigba ti ipade Total Experiece
yoo ma waye fun igba akọkọ, ọkunrin naa wa, o si gba itusilẹ lọwọ Ọlọrun. Ojisẹ
Olorun, Deola Philips, sọ asọtẹlẹ wi pe, okunrin naa yoo wa si ipade odun yii
lati wa jẹri.
Si iyalẹnu awọn eniyan ati
fun ogo Ọlọrun, ọkunrin yii pada wa lati wa sọ bi agbara Ọlọrun se sọji pada
ninu aisan ọlọjọ pipẹ naa.
Ẹri ọkunrin naa mu ọkan
ọpọlọpọ jigiri, igbagbọ awon eniyan lati ri iyanu gba si tun ga sii. Lẹyin eyi
ni awon eniyan gbe orin iyin soke fun isẹ iyanu nla ti Oluwa se. Eyi n lọ lọwọ
ni Pasito Deola Philips gun ori pẹpẹ.
Awon eniyan ka ọwọ
won soke, won si sọ wi pe, “Oluwa lo gaju gigaju lọ, Oluwa lo tobi ju titobiju
lo…
Akọkọ ni wi pe, Jesu
wa fun wa ni iye ainipẹkun, o si tọka si iwe John3:16. Nibi ni bibeli ti n sọ
wi pe, ẹnikẹni to ba gba Jesu gbọ, kii yoo segbe sugbon yoo ni iye ainipekun.
Pasito Deola salaye wi pe, iye ainipekun ko so nipa ìyè ti ko lopin nikan;
eleyii ti eniyan yoo ma gbe lai ni opin. O ni iye ainipekun yii nise apejuwe
iru iye ti Olorun orun ni, eleyii ti Jesu naa ni. O ni iru iye yii gan-an ni
Jesu mu wa saye fun ẹda eniyan.
Koko keji ninu waasu
rẹ ni wi pe, Jesu wa fun wa ni idalare. Eleyii ni ojise Olorun si fi idi rẹ
mulẹ ninu iwe Romu 5:1-2. Pasito Deola salaye wi pe, ọ tọ ni ki eniyan
sẹ, ki ẹni naa si gba idarijin. Bakan naa lo tun wi pe, ọ tọ ni ki eniyan sẹ,
ki won si da lare wi pe ko jẹbi ẹsẹ naa rara, eyi ni wi pe, ẹni naa ko dẹsẹ
rara.
O ni iru idalare yii
gan-an ni Kristẹni rigba ninu igbala Jesu omo Olorun. O ni, nikete ti a
jewọ Jesu ni Oluwa, ko si akosilẹ fun ẹsẹ wa mọ rara.
Koko kẹta ninu waasu
naa, eleyii to n sọ nipa lara ohun pataki ti Jesu Oluwa wa se laye, ni lati mu
ibasepọ pelu Olorun wa fun awon eniyan.
Lati mu wa di ẹbi
Olorun ati lati jẹ alabapin ibukun rẹ. Alaye yii ni a le ri ninu 1 John1:3.
Nikete ti Pasito
Deola Philips pari iwaasu rẹ, bẹẹ lo bẹrẹ si ni gbadura ni oruko nla ti Jesu.
Lọwọ kan naa ni awon ọrọ imọ n jade lẹnu rẹ. O sọ nipa orisii ailera awon
eniyan ati ohun ti Olorun se nipa rẹ lọwọlọwọ.
Nigba to setan, orin
iyin tun goke. Awon eniyan dunnu, won yin Oluwa Olorun pẹlu ohun oke, ka to
seju pẹ ẹ, awon arọ ti n dide lori aga won. Awon ti won dubulẹ aisan ti n fo
fayọ.
Aimoye awon eniyan ti
won ba isẹlẹ iyanu oju ẹsẹ pade ti n sare sita. Ariwo ti n ta lapatun ati
lapasi, eleyii ti n jẹri wi pe iyanu kan sẹlẹ kaakiri gbogbo agbegbe naa.
O ku diẹ ki awon
eniyan maa jẹri agbara Olorun, ni ibukun bẹrẹ si ni sokalẹ lati oju orun bi omi
ojo si ori awon eniyan. Eleyii jẹ ohun to jọ ọpọlọpọ loju. Gbogbo ara awon
eniyan tutu bẹẹ lorin iyin tun goke ju atẹyin wa lọ.
Awon eniyan ti won
jade lati fi aye won fun Jesu ko lonka. Gbogbo won pata ni won jẹwo Jesu gẹgẹ
bi Oluwa ati Olugbala ti won si setan lati maa rin ni ilana rẹ titi ọjọ aye won.
Ogo ni fun Oluwa, oba
to sọrọ, ti agbara Rẹ si tẹle ọrọ Rẹ. Hallelujah!
0 comments:
Post a Comment