Ajiyinrere Samuel Oyindamola |
Orisiirisii ọna ni ijọba okunkun n lo lati ba awon eniyan
laye jẹ. Lara irinsẹ pataki kan ti ẹmi okunkun n lo ni orin. Aimoye orin lo wa lode oni to jẹ wi pe esu n
lo lati ri ayanmọ awon eniyan mọle, eleyii ti awon eniyan ko si fura.
Orisii
orin ti a n gbọ ni gbogbo igba, eleyii ti a si n ko lẹnu ko ipa pataki ninu
igbe aye wa.
Eniyan le ba isegun pade
ninu orin iyin to ni imisi Oluwa ninu. Bakan naa ni eniyan le ri iwosan gba
lati inu ojulowo orin to sokale wa lati ori itẹ mimọ.
Yato si eleyii, orin tun le mu
okan to ti sako lo pada wale lati ma rin ni ọna Oluwa. Idakeji rẹ ni fun awon orin to wa lati ijọba okunkun. Aimoye ọdọ iwoyi ni won si ti sọ ọjọ iwaju won nu latari awon orin to ti ijoba okunkun wa ti won gbọ ti won si n kọ lẹnu.
Mo ti n ko awon alaye
iwadii mi jọ nipa Samuel Oyindamola. Ọdomọde olorin ẹmi ti Olorun n lo fun iran
ikeyin yii. Ti asiko ba to, ma salaye iransẹ nla ti Oba oke gbe le e lọwọ,
eleyii ti irawọ rẹ ti bẹrẹ si ni tan loju
ọrun bayii.
Sugbọn ko to di akoko naa,
maa royin ki ẹ gbo IYAOTOSIMI, orin tuntun lati inu awo to pe ni SEMI LOGO. Mo
si gbadura wi pe, bi ẹ se n gbọ orin naa, ìyà, wahala, idaamu, fitinati, ifooro,
oriburuku ko ni to si yin ati idile yin. Amin
Ninu awon iroyin mii to so nipa Samuel Oyindamola Olabamiji ni yii:
0 comments:
Post a Comment