Lana, 27-05-16, ojo ayajo awon ewe
agbaye, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja II gbalejo awon omode lati ba
won yo ayo idunnu to wole to won.
Ipade
Arole Odua pelu awon ewe yii tun mu opolopo awon eniyan loye nipa eni
ti Baba Adeola je. Gbogbo ona ni Ojaja oko Wuraola fi n ba awon omo wewe
sere lai bikita nipa aso funfun, aso ola, ti n be lorun re.
Ojo
ketadinlogun osu kinni odun 2016 ni Ooni Ojaja se abewo siluu Oyo.
Eleyii to waye leyin bi odun mokandilogorin (79yrs) ti iru re ti sele
keyin.
Bakan naa lo si ti so ninu awon oro re kan wi pe, oun ko wa lati wa jija agba pelu enikeni.
Awon
igbese Ooni tuntun eleyii ti n se afihan isokan, ife otito, irepo ati
idagbasoke laaarin omo Yoruba tun bo mu opolopo feran oba ti won bi
lodun 1974.
Awon
onwoye si salaye wi pe, ti Ooni ba le tesiwaju ninu awon igbese re yii
gege bi asaaju rere, afaimo ki okiki Ojaja II ma ju ti gbogbo Ooni to ti
je saaju lo niluu Ile Ife nibi ojumo ti gbe n mo wa.
Ibi yii lemi a ti gbe dake. E ma gbagbe wi pe, Olayemi Oniroyin ni oruko temi.
Iran Yoruba sini iran mi, iran awon ologbon ati onilaakaye eda.
E ku odun awon ewe. Omo wa ko ni yanku. Ase
0 comments:
Post a Comment