Taa ba n ranti eni ti nbe laye, o ye ka tun maa seranti awon eniyan pataki ti won ti koja lo sorun. Oni ojo karun-un osu karun odun 2016 lo pe odun kefa ti Aare ana, Umaru Musa Yar'Adua ti koja lo sorun.
Ojo kerindinlogun osu kejo odun 1951 ni won bi Musa sile aye.
O si ti je gomina ipinle Kastina saaju, laaarin odun 1999 si 2007, ko to gbe apoti idibo aare lodun 2007.
Iku mu Musa Yar'Adua lo latari aisan olojo pipe kan to ti n ba finra. Ni awon akoko idubule aisan re yii, won gbe lo siluu Saudi fun itoju.
Sugbon nigba to di ojo keji osu karun-un odun 2010 ni won daa pada wa sile. Nigba ti akuko si ko leyin omokunrin lojo karun-un osu karun-un odun 2010.
Lara awon aseyori ti ko se foju pare ninu isejoba Musa Yar'Adua ni bo se fopin si awon omo ogun agbebon ti agbegbe Niger Delta.
Gege bi oro awon Yoruba, ko si eni waye ti ko ni ku. Iku o peni a n pe, iku o si pa eni ti n pe ni. Oun to se pataki ju loun taa gbe ile aye se.
Ki Oba mimo dele fawon to ti lo.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment