Obafemi Martins |
Ọpọlọpọ awon eniyan ti bẹrẹ
si ni juko abuku si Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ooni ile Ife, bayii pẹlu bo se
se abẹwo si ogbontarigi agbaboolu Naijiria, Obafemi Martins.
Sebi won ni inu ẹni ki i
dun ka pa mọra, Obagoal lo ju foto Ooni sori ayelujara ni akoko ti oba to kawe
gboye ninu imọ
isiro owó se abẹwo si i.
O jọ bi ẹni wi pe abewo Arole
Oduduwa sile agbabọọlu ti n gba bọọlu jẹun niluu China ko fi taratara tẹ awon
kan lọrun pelu awon iriwisi to jade leyin ti foto naa ti doju iworan.
Awon kan ni awon abẹwo
Ooni to ti n se saaju mu itumo gidi dani, nitori wi pe, awon abewo naa fi ifẹ
mulẹ laaarin awon saaju ile Yoruba ni. Ninu ero won, won ni ki i wa sebi ki ọba
ma fo jade fokifoki kaakiri ma ki taja-teran nile. Won ni iru awon abewo yii dabi igba ti oba
alaye naa n fi ori ade wọle lasan ni.
Sugbon sa, ohun to koju sẹnikan
eyin lo kọ si awon mii. Awon kan ni a ko le da Ooni asiko yii lebi nitori wi
pe, enikeni ko mo ajọsepọ to wa laarin Ooni Ojaja II pelu Obafemi saaju ko to jọba.
Sebi awon Yoruba naa lo wi pe, atanamana ko to atonimoni.
Awon kan tun ri
gege bi emi irẹlẹ eleyii ti won lo n fi Ooni Adeyeye han gege bi asaaju rere
nile Yoruba.
Akoko ti Obafemi se abewo si Oba n'Ile Ife |
0 comments:
Post a Comment