Baasọrọ Ilẹ Yoruba, Otunba Kola Olootu |
Ka ma parọ, oloju alagbara
to le gbe olumọ sare. Oloju ẹni le fọwọ lasan fọnna ayafi ẹni èdì ba n di tabi
ko jẹ Sango olukoso ọkọ Ọya. Lati ilẹ yii to fi doke okun, oloju sọrọsọrọ to le wi igba
ọrọ lete lai mu takada dani, a fi Sikiru ọmọ Olawuwo, Akolawole Olootu omo
Adabanija, Baasọrọ Ilẹ Yoruba pata.
Ẹni Akolawole Olootu ba polowo oja rẹ ti o
ba ta, bẹni naa lori CNN agbaye iro lasan lo pa. Ọgbọn ori ko dabi ẹni oba oke
fun se. Ka pede asayan ko dabi agbekalẹ to mọyan lori. Imọ si sàgbà ẹbun lọjọkọjọ, to ba jọ bi iro ẹni ẹ ba ri ẹ bi. To ba wa
jẹ wi pe won gba kofẹsọ ninu ede pipe ni, Olootu ti to lẹni a ba maa jiki b’oosa.
Oba Saliu ati Olootu, nigba to ku diẹ ki baba gori itẹ |
Bo tilẹ jẹ wi pe, o ti pe
ti Kola Olootu ti gbe oye Baasọrọ lori,
sugbon Ọtunba ti lọ wuye oye naa bayii gẹgẹ
bi agbekalẹ isẹdalẹ Yoruba niwaju Oba Saliu Adetunji Aje Oguguniso 1, Olubadan tilẹ Ibadan.
Kola Olootu ninu yara agbara |
Ni oruko mi ati awon igbimọ
mi pata, mo ki Baba Oloye ku oriire oye tuntun.
0 comments:
Post a Comment