Smiley face

Igbeyawo Ọmọọba Kazeem Akadi dun yungbayungba bi oyin

Ọmọọba Kazeem Akadi ati Opeyemi
Gbogbo wa pata la wa n'Ibadan lopin ọsẹ to kọja (05-06-16) lati ba Ọmọọba Kazeem ati aya rẹ, Ọpeyemi, yọ fun eto igbeyawo (nikkah) won to waye.

Kosi ohun to dabi yigi eleyii ti won gbe lori ifẹ otitọ ati ọrọ Olorun to ye kooro. Leyin ti awon Alfa gba awon tọkọ-taya tuntun lamọran nipa ojuse won ninu ile lati mu ki igbeyawo won duro sinsin, aimoye adura lo tun waye fun toko-taya tuntun naa.

Ọmọọba Kazeem: Ọdomọde olowo ti kii pariwo
Won ni Ijebu ti n nawo isẹmbaye kowo dollar to de. Igba towo dollar de tan lowo Ijebu tun yanpian. Ko jọ ni loju nigba tawon idile Ọmọọba Akadi bẹrẹ si ni fon owo loju agbo, apo awon Alaafa ati Ladani lo kun bamubamu nigba ti awon eniyan jẹun ti won mu pelu ayọ nla.

Mo tilẹ tun ri awon kan ti won fi ọti waini sinwọ lẹyin agbo. Ka ma parọ, ariya san ni'Ibadan nile Oluyọle Oba Aje Ogugunisọ 1.
Lopin ohun gbogbo, mo duro titi mo fi ri daju wi pe won gbe sabuke le Ọmọọba Kazeem lọwo, eleyii to n fidi rẹ mule wi pe, Opeyemi ti daya rẹ lojulowo.

Adura wa ni wi pe, ire ati ayọ ni yoo kun inu igbeyawo naa. Amin.


Olayemi Olatilewa ni oruko temi. "Mọntashi" ni mo si n lo funse iroyin ti n gbemi saye. 


Njẹ ki lo n je "Mọntashi"

Awon Alfa ti mo pade lode Omooba Akadi ni ọpọlọ to kun fọfọ bi ataare ni  jẹ "Mọntashi" lede Larubawa.


E ku ikalẹ!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments: