Smiley face

"IWURE AYAJO OJO IBI MI"- Adeleke Ademola

Aimoye awon eniyan ni won ba Alagba Adeleke Ademola yo lanaa,16-06-2016, fun ayajo ojo ibi won to ko. 

Bi awon eniyan se n se adura bee ni won tun ba won dupe lowo Olorun.
Gege bi oro awon agba,"tawo ba ki fun ni, a ki fawo pada ni".

Nibayii, Omooba Ademola ti wure fun ara re bakan naa ni won kosi gbagbe awon ololufe won pata.
Iwure naa ni yii:

"Ori pele o, Atete niran, A tete gbe ni k'Oosa, Ko s'Orisa tii da nii gbe, lehin Ori eni, Ori mi mo pe o, Ori jare dakun, dabo, f'iye de'nu, f'iye de'sale ikun, ma je k'a r'ibi iku, Ase.

Ma je k'a r'ibi arun. Ma je ka r'ibi ofo. Ori jare dakun, dabo, f'iye de'nu, fiye de'sale ikun. Ori fi'le awa bunwa, Ori jowo jare f'ona awa bunwa, f'ise awa yin wa, f'owo wo wa loko lodo. 

Ori pele o, abaniwaye ma see gbagbe, iwo naa la sin wa'le Aye, Ori eja l'eja fii la 'buu ja, Ori laa fi s'owo asejere, 

Eye kii fo, ko f'Ori so'gi Ori wa, dakun dabo, jare fiye de' nu.

Ori wa, jare ma gb'abode, Ori wa, waa gb'ere kowa, ya wa ya ibi, ya ibi ya wa.
Nitori Ori agbe nii gbe're e pade agbe, Ori aluko nii gbe're e pade aluko, n je mo p'adie OPIPI b'Ori loni, iku ye l'Ori awa, arun ye l'Ori awa, ofo ye l'Ori awa, ki gbogbo ibi o ye l'Ori awa o, Ori agbe lo f'iye re b'aro,

Ori aluko lo f'iye re b'osun, Ori awa tete waa gbe're t'awa kowa, Ori wa ko s'oro wa d'ayo,
lle igbin kii gbo'na, lle awa ko nii gbo'na, Ori ma jek'agbako o kowa, Ori bawa tun oran-an tawa se,
Ori bawa gb'oran-an tawa yewo si 're, ma je a r' ofo, ma je a p'ofo, ma je a gunle s'ebute ofo.

Alobo ni t'ada, Oko ni yo sun s'oko, Ada yoo bo, Ori ma sai pa alo at'abo tawa mo, ka s'owo k'a j'ere, k'a b'ode pade, ki t'owo t'omo bawa s'ohun rere,

Ori jowo sinwa, koo ma pada lehin wa, Ori iwo nikan lo ba ni w'aye duro ti'ni, bawa gb'eru tawa d'Ori, Ori se'le awa ni're,

Ori s'ona tawa ni're, Olojo oni o gbo o, Olugb'ohun naa o gbo o,
Olodumare ire lawa yan o, aseyi s'amodun o, ni'woyi amodun, akotun ire ni'le tiwa.

Awi dun mon-mon laa royin Oyin, Mon-ran-in, Mon-ran-in laa royin iyo, ladun ladun laa maa gburo araa wa.

Yoruba Dun bi Oyin ni."

















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment