M&C FM 106.5 |
Ile isẹ redio King Sunny Ade ni won ti
ko sita bayii bi ọmọ tuntun jojolo nipinle Ondo lọjọ kokanlelogun osu
kẹfa odun yii, 21-06-16.
Lara
awon alejo pataki nibi ifilọlẹ ile ise redio naa ni Gomina Olusegun
Mimiko ti ipinle Ondo. Ile ise radio ti won pe ni M&C FM (Music
& Culture) ni yoo ma se igbelarugẹ fun orin ati asa ibile Yooba
pata. Ori ikanni 106.5FM ni redio naa yoo si ti ma dun seti araye.
Gẹgẹ
bi itọpinpin ile ise redio Cool FM to wa niluu Eko, eleyii to jade ninu
okan ninu awon iroyin won ni ibẹrẹ odun yii, won ni ile ise redio ti
Omooba Sunday Adeniyi, eni ti a bi lodun 1946, n pete rẹ yii ni yoo jẹ
redio akọkọ ni orileede Naijiria ti n se igbelaruge fun orin ati asa ilẹ
wa.
Wayio, awon eniyan ipinle Ondo ti bere si ni gbe orinyin fun ọba orin juju pelu bi ko se gbagbe ibi won ti gbe bi i lọmọ.
Iru ara ti Sunny Ade da yii naa lati ri awon kan naa lagbo amuludun, yala orin tabi ise tiata, ti gbese saaju.
Yinka
Ayefele olorin juju naa ti da Fresh FM sile niluu Ibadan nigba ti
telifisan Tunde Kelani duro gbangba lori ayelujara. Gbenga Adewusi (Baba
Itunnu) naa o gbeyin pelu idasilẹ mohunmaworan Yoruba Swaga lori
Consat to kari aye.
Olayemi
Oniroyin ni oruko mi. Ibi ni maa si ti duro na.
Awon kan le je kapenta,
awon kan si le jẹ ọndateka. Mo tile tun gbọ nipa awon kan ti won pe ni
atunrọta.
Sugbon ni temi, iroyin laye mi. Walahi! O n ba mi sun ni,bee lo n ba mi ji.
E ku ikale!
Well done sir.
ReplyDeleteThanks
ReplyDelete